L'ọjọ Ajinde: Ọwọ tẹ afurasi ajinigbe l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 18, 2022

L'ọjọ Ajinde: Ọwọ tẹ afurasi ajinigbe l'Abẹokuta


Ka ni ki i ṣe ọpẹlọpẹ awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn tete ranṣẹ s'awọn ọlọpaa ni, boya ni ọkunrin kan ti wọn fura si pe ajinigbe ni ko ba ti gbagbe pe oun wa sile aye ri.


Iya ko to lilu fun ọkunrin naa lagbegbe Idi-Ori, ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.

AWIKONKO gbọ pe ṣe ni ọkunrin naa n kọja lọ ni agbegbe yii, ko to di pe ọkan lara awọn ti wọn jigbe laipẹ yii da a mọ, to si pariwo rẹ sita f'awọn araalu, to si ni ọkunrin naa pẹlu awọn ajinigbe ẹgbẹ rẹ gba owo nla lọwọ oun ko to di pe wọn foun silẹ lahamọ wọn.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, Olubukọla sọ pe ni kete ti ẹni naa ti pariwo sita, l'awọn eeyan adugbo ti dide, ti wọn si bẹrẹ sii dana iya fun un.
 
Igba ti wọn lo ku diẹ ki wọn dana sun un l'awọn ọlọpaa ti wọn ranṣẹ pe sare debẹ, ti wọn si gba a silẹ.
 
Nigba to n f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ, Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe lotitọ ni iṣẹlẹ ọhun,. ati pe awọn ko ti i le f'idi otitọ mulẹ boya ajinigbe ni ọkunrin naa lotitọ.

O ni iwadii ti awọn ba ṣe ni yoo jẹ k'awọn ri ojutuu si ọrọ naa, bẹẹ lo gba awọn araalu lamọran lati ma ṣe maa ṣe idajọ ọwọ ara wọn nigbakugba ti wọn ba ti mu afurasi ọdaran, ko ma jẹ pe alaiṣẹ ni yoo kagbako.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI