Wahala Onimọto l'Ekoo: Ijọba Eko ni iṣẹ pupọ lati ṣe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 18, 2022

Wahala Onimọto l'Ekoo: Ijọba Eko ni iṣẹ pupọ lati ṣe


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, bi ijọba ipinlẹ Eko ko ba tete wa nnkan ṣe si ọrọ wahala awọn onimọto to n f'ojoojumọ waye nipinlẹ naa, afaimọ ni ko ma jẹ pe omi yoo pada wọ igbin lẹnu, ki ọrọ wahala naa ma si pada di ogun abẹle ti agbara ko ni i ka mọ.

Ki i ṣe ti ẹnu tabi asọdun pe ẹgbẹ awakọ National Union of Road Transport Workers, NURTW jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹka to rọ mọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede yii, iyẹn Nigeria Labour Congress.

Ojuṣe ti wọn si n ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju Naijiria ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, paapaa lẹka eto ọrọ aje.

Fun idi eyi, awọn wahala ati awuyewuye to n waye ninu ẹgbẹ naa, ẹka ti ipinlẹ Eko n fẹ abojuto gidi lai fi igba kan bo ọkan ninu.

Ko si nnkan meji to jẹ ipilẹ wahala to n f'ojoojumọ ṣẹlẹ yii, bi ko ṣe bi ẹni to jẹ alaga wọn tẹlẹ, Ọgbẹni Musiliu Akinsanya iyẹn MC Oluọmọ ko ṣe fẹẹ gba lati jẹ ki ọkan lara awọn ẹka ẹgbẹ NURTW naa, Tricycles Owners and Operators Association of Nigeria, TOOAN nipinlẹ Eko da duro, eyi ko si yẹ ko ri bẹẹ.

A tiẹ gbọ pe ki MC Oluọmọ funra rẹ to o di alaga apapọ fun ẹgbẹ NURTW, ni wahala yii ti bẹrẹ, lori bi awọn oloye ẹgbẹ ṣe n sọ pe awọn ko le gba ki TOOAN da duro.

Gbogbo akitiyan awọn oloye ẹgbẹ naa lapapọ lati ilu Abuja lati jẹ ki MC Oluọmọ pana wahala naa lo ja si pabo, eyi to mu ki wọn fi ofin da a duro fun igba diẹ, ti wọn ni ko lọ rọ kunle.

Lẹyin eyi ni Oluọmọ gbe igbesẹ miran, to si ko gbogbo ọmọ ẹgbẹ onimọto NURTW kuro nibẹ lati da duro. Ko pẹ ti wọn kede idaduro wọn ni ijọba ipinlẹ Eko labẹ akoso Gomina Babajide Sanwo-Olu da ẹgbẹ onimọto ti ipinlẹ naa silẹ, to si fi MC Oluọmọ ṣe olori wọn.


Ko pẹ ti Gomina Sanwo-Olu kede MC Oluọmọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ onimọto Eko ni wahala bẹrẹ sii ṣẹlẹ, to di pe awọn ọmọ ẹgbẹ bẹrẹ sii doju ija kọ awọn ti TOOAN lagbegbe Fagba si Iju Iṣaga nipinlẹ ọhun.

Ni bayii, a fi ki ijọba Eko tun ero rẹ pa lori igbesẹ yii, ko si wa iyanju ayeraye si ọrọ wahala naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI