Ramadaani: Gomina AbdulRazaq bawọn ẹlẹsin Musulumi yọ, bẹẹ lo tun gba wọn lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 2, 2022

Ramadaani: Gomina AbdulRazaq bawọn ẹlẹsin Musulumi yọ, bẹẹ lo tun gba wọn lamọran


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin Musulumi kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ Kwara yọ lori aawẹ Ramadaani ọlọdọọdun to wọle wẹrẹ.

Ninu atẹjade ti gomina fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ yii lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, o jẹ ko di mimọ pe anfaani nla ni aawẹ Ramadaani ti ọdun yii yoo mu wa, nitori apẹẹrẹ ti fi han.

AbdulRazaq wa gba gbogbo eeyan lamọran lati sunmọ Ọlọrun, ki wọn si ṣe aanu fun awọn alaini, ati pe ki wọn lo anfaani aawẹ naa lati tọrọ aforijin lọwọ Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI