Ko yẹ ki iku Ayinla Ọmọwura jẹ kayeefi fun wa - Ẹgbẹ AOLERC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, April 1, 2022

Ko yẹ ki iku Ayinla Ọmọwura jẹ kayeefi fun wa - Ẹgbẹ AOLERC


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Ayinla Ọmọwura Legacy and Research Centre (AOLERC) ti sọ ọ di mimọ pe ko yẹ ki iku Oloogbe, Alaaji Waidi Yusuf Ayinla Ọmọwura ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Anigilaje jẹ ajoji si ọpọ awọn ololufẹ, paapaa mọlẹbi rẹ.

Alagba Rabb Adeṣina to jẹ ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ naa lo sọ eyi di mimọ nibi ipade awọn oniroyin ti ẹgbẹ naa gbe kalẹ ninu gbọngan ipade ti Nigerian Institute of Personnel Management to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọbọ ti i ṣe Tọsidee, ọsẹ yii.

Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe idi pataki t'awọn fi gbe ẹgbẹ naa kalẹ ni lati ma ba a jẹ ki ede, aṣa ati ede Yoruba parun lojiji, nitori pe awọn iṣẹ ti oloogbe naa ti ṣe silẹ ko to o ku, lo fi ṣe igbelarugẹ ẹwa ede ati aṣa Yoruba larugẹ.

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni; Alaga agba, Ọlaniyi Ọlagoke; Alaaji Rabb Adeṣina, Alaaji Ọlaniyi Ọlagoke, Ọmọwe Kọla Adeṣina, Ayọ Ọjẹniyi, Ọjọgbọn Oyetọla Oniwide, Onimọ-ẹrọ Akinlawọn Akintunde, Alaaji Hassan Rilwan, Alaaja Halimat Ọmọwura, Alagba Emmanuel Ọdẹnusi to ka gbogbo orin Ayinla Ọmọwura silẹ nigba aye ẹ.


Ọmọ bibi ilu Itoko naa, to jẹ agba olori Apala nni lo jade laye lọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun 1980.
 
Ẹgbẹ naa sọ pe gbogbo awọn awo orin Oloogbe Anigilaje l'awọn ni ni erongba lati sọ di ohun ti awọn eeyan yoo maa fi ṣe iwadiinipa igbelarugẹ aṣa, ede, iṣe ilẹ Yoruba, eyi ti wọn l'awọn ko fẹ ko parun.

Nibẹ ni wọn ti gba awọn agbaagba, obi ati alagbatọ, to fi mọ awọn alẹnulọrọ nilẹ Yoruba lati wa gbogbo ọna ti ohun ajogunba ilẹ Yoruba ko fi ni i parẹ lojiji.

Nigba to n sọrọ, alaga igbimọ iṣakoso ẹgbẹ naa, Oloye Ọlaniyi Ọlagoke sọ pe awọn ololufẹ orin Oloogbe Ayinla Ọmọwura l'awọn pinnu lati da ẹgbẹ naa silẹ, ti a si tun gbọ pe wọn ti n kọ iwe tuntun nipa orin ati igbesi aye Anigilaje lọna to yatọ si eyi ti awọn onkọwe kan ti kọ sẹyin, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn lọrun to.
 
Ọlagoke sọ pe awọn orin Ayinla lo fi gbe aṣa Yoruba larugẹ kaakiri agbaye, to si di ohun ti aye, paapaa awọn oyinbo alawọ funfun n wa kọ.
 
Ninu ọrọ tirẹ, Oloye Rabb Adebiyi sọ pe iku Ayinla ko yẹ ko jẹ ohun to n yani lẹnu nitori pe akikanju ati alagbara eeyan ni, to si ni awọn ko si ojiṣẹ Ọlọrun kankan ninu itan to fọwọ rọri ku.
 
O ni bi ko ṣe si ojiṣẹ Ọlọrun to fọwọ rọri ku ninu awọn iwe mimọ mejeeji ati iwe itan, bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ Ayinla jẹ, nitori pe iku alagbara lo ku lọjọ to tẹri gbaṣọ, to si ni igbesẹ ti awọn gbe yii ni lati maa fi ṣe iranti ẹ titilai.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI