AbdulRazaq bu ọwọ́ lu ìgbéga f'áwọn olùkọ́ TESCOM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 24, 2022

AbdulRazaq bu ọwọ́ lu ìgbéga f'áwọn olùkọ́ TESCOM


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu igbega fun gbogbo awọn olukọ ti wọn wa labẹ akoso Teaching Service Commission, iyẹn TESCOM ti wọn yẹ lati gba igbega.

A gbọ pe gbogbo awọn olukọ TESCOM, ti wọn ti kun oju oṣuwọn lati gba igbega bẹrẹ lati ọdun 2018, 2019, 2020 ati 2021 ni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe aaye ṣi silẹ fun wọn lati kopa ninu eto idanwo igbega ti yoo waye laipẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ti yoo kopa ninu eto idanwo igbega naa din diẹ ni ẹgbẹrun meje aabọ (7,493), gẹgẹ bi ipinnu ijọba lati maa ri sọrọ alaafia ati igbayegbadun awọn oṣiṣẹ.

Nigba to n sọrọ ninu atẹjade kan to fi sita, alaga TESCOM, Malaamu Bello Taoheed Abubakar gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq bi ko ṣe n fi ẹtọ wọn dun wọn, to si tun n fun wọn l'anfaani lati ṣe ojuṣe wọn.

O wa jẹ ko di mimọ pe eto ati ilana fun idanwo igbega ọhun l'awọn yoo fi sita laipẹ, ti yoo sì bẹrẹ lakọtun laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI