Tántálá gba ààmì ẹ̀yẹ 'sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ to gbajúmọ̀ jùlọ n'ìpínlẹ̀ Ògùn' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 22, 2022

Tántálá gba ààmì ẹ̀yẹ 'sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ to gbajúmọ̀ jùlọ n'ìpínlẹ̀ Ògùn'


Ẹsẹ ko gbero ni gbọngan ayẹyẹ Amazing Grace to wa ladugbo Kufori Olubi, Adigbẹ niluu Abẹokuta lonii tii ṣe Aiku, Sannde, nibi ti gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio nni, Oloye Sunday Ogunṣọla, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Tantala ti gba awọọdu nla.

Ileeṣẹ kan to mọ nipa rira ati tita ile ati ilẹ, Sweet Estate lo fi aami ẹyẹ da Oloye Sunday Ogunṣọla, Tantala lọla lati fi mọ riri ipa to ko ninu idagbasoke eto ọrọ aje ileeṣẹ naa.

Aami ẹyẹ 'Sọrọsọrọ to gbajumọ daadaa l'ọdun 2022' ni ileeṣẹ naa fi da Tantala lọla, nibi ayẹyẹ ọdun karun-un ti wọn da ileeṣẹ Sweet Estate silẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.


Nigba to n sọrọ nipa idi to fi f'aami ẹyẹ ọhun da Tantala lọla, Oloye Olumide Falọla to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Sweet Estate ṣalaye pe iwadii kikun ti wọn ṣe lo fi han pe ọkunrin naa ni aye n gbọ daadaa lasiko yii.

O sọ pe nigba ti wọn da ileeṣẹ naa silẹ lọdun marun sẹyin, Tantala nikan ni sọrọsọrọ to duro ti wọn, to si fun awọn ni onibara to le lẹgbẹrun meji, ti wọn ba won dowopọ.Nigba toun naa n sọrọ, Oloye Tantala sọ pe ohun teeyan ba mọ-ọn ṣe ni ko tẹsiwaju, nitori pe Ọlọrun lo n fun ni l'ẹbun.

O ni ki i ṣe pe oun fi owo ra aami ẹyẹ naa, bi ko ṣe pe awọn ipa rere toun n ko nipasẹ eto ori redio ti Isin Alajumọṣe lo n gbe iwa rere oun larugẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI