Amuzu àtàwọn èèyàn rẹ̀ n tan ara wọn lásán ni, ayédèrú ọmọ oyè lòún àti àwọn èèyàn rẹ̀ l'ẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP - Amósùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 25, 2022

Amuzu àtàwọn èèyàn rẹ̀ n tan ara wọn lásán ni, ayédèrú ọmọ oyè lòún àti àwọn èèyàn rẹ̀ l'ẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP - Amósùn


Oludije sipo ile igbimọ aṣoju-ṣofin lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọnarebu Akeem Amosun ti sọ pe gbogbo awọn to n pe ara wọn lọmọ oye f'ẹgbẹ oṣelu naa kan n tan ara wọn lasan ni, wọn ki i ṣe ojulowo ọmọ oye.

O ni awuruju eto idibo abẹle ni ọpọ wọn ṣe, eyi to tako ofin ẹgbẹ oṣelu PDP, to si ni ko f'ẹsẹ mulẹ.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu PDP gbe eto idibo abẹle kalẹ lati fi yan awọn ọmọ oye ti yoo du ipo Aṣofin, iyẹn Sẹnetọ; aṣoju-ṣofin agba tii ṣe House of Reps ati aṣoju-ṣofin kekere, ti wọn tun n pe ni House of Assembly.

Gbọngan ayẹyẹ ti ile ikawe aarẹ, iyẹn Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta ni eto idibo abẹle ọhun ti waye, gẹgẹ bi awọn oloye ẹgbẹ ti ṣe kede rẹ ṣaaju.

Yatọ si eyi, a gbọ pe Gbọngan Centinary to ni Ake, Abẹokuta ni wọn ti ṣe eto idibo abẹle fawọn ti Abẹokuta South, nibi ti Akeem Amosu, Sọlomọn Ẹnilọlobọ, ati Suraj Adeyẹmi ti jawe olubori, iyẹn lọjọ Aiku, Sannde.

Dada Kọlawọle Ọduntan ni wọn lo jawe olubori fun ipo Sẹnetọ lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nibẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Awọn oṣiṣẹ eleto idibo, iyẹn INEC la gbọ pe wọn ṣakoso eto idibo abẹle ọhun, nibi ti awọn eleto aabo loriṣiriṣi ti pese eto aabo to peye fun gbogbo wọn, ti wọn si ni akọsilẹ nipa rẹ.

Lẹyin ajọ INEC at'awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP kede awọn ọmọ oye tan ni wọn sọ pe awọn miran ko ara wọn jọ, ti wọn si gba ileeṣẹ ẹgbẹ naa lọ lati lọ gbe eto idibo abẹle miran kalẹ, nibi ti wọn ti kede awọn ọmọ oye miran faraye.

Lara awọn ti wọn kede ni Toyin Amuzu fun ipo aṣoju-ṣofin agba lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ti a si gbọ pe sẹ lo ya pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ lẹnu.

Kikede ti wọn kede awọn ọmọ oye miran yii lalẹ ọjọ Aje, Mọnde lo mu ki awọn ọmọ oye ti wọn ti kede wọn ṣaaju dide lati gba ileeṣẹ awọn akọroyin ipinlẹ naa lọ ni Oke-Ilewo lati fi idi otitọ mulẹ.

Lara awọn to wa nibẹ ni Ọnarebu Akeem Akintayọ Amosun ti wọn dibo yan lati ṣoju ẹkun Abẹokuta South; Ọnarebu Samuel Oluwafemi Abiọdun ti ẹkun Abẹokuta North/Obafẹmi Owode ati Ọdeda.

Awọn yooku ni Solomon Ẹnilọlobọ, Dada Kọlawọle Ọduntan, Suraj Adeyẹmi, Gbenga Ṣoyọde, Makanjuọla Daniel at'awọn miran.

Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn ti wọn gbe eto idibo abẹle kalẹ ni ọfiisi PDP, iyẹn nibi ti ko ti si labẹ ofin lo jẹ pe ṣe ni wọn n tan ara wọn jẹ lasan ni.

Akeem Amosun ninu ọrọ rẹ sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun wọn pe awọn miran tun dide lati maa pe ara wọn lọmọ oye ẹgbẹ lẹyin eto idibo abẹle ti kọkọ waye.

O ni ofin ẹgbẹ l'awọn tẹle, ti awọn oludibo kaakiri wọọdu 236 to wa n'ipinlẹ Ogun ti wa dibo nibi ti ẹgbẹ fi ẹnu ko si, ati pe alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Sikirulai Ogundele ti fi lẹta ranṣẹ si ajọ INEC ṣaaju ọjọ idibo abẹle.

Bakan naa lo sọ pe ko si ajọ INEC ati oṣiṣẹ eto aabo nibi ti wọn ti gbe eto idibo abẹle awuruju kalẹ, ti wọn si kede awọn ọmọ oye irọ miran.

Gbogbo awọn eeyan yii wa ṣe ikilọ fun awọn alakoso ẹgbẹ lapapọ lati tete gbe igbesẹ to yẹ, bi bẹẹ kọ, awọn yoo gba ile ẹjọ lọ lati tako wọn, nitori pe awọn fẹran ofin pupọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI