Sẹgun Ṣowunmi di ọmọ oye s'ipo gomina l'ẹgbẹ oṣelu PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 25, 2022

Sẹgun Ṣowunmi di ọmọ oye s'ipo gomina l'ẹgbẹ oṣelu PDP


Lẹyin ọpọlọpọ wahala ati oriṣiriṣi awuyewuye to ti waye lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Ogun, sibẹ, ajọ eleto idibo ti kede agbẹnusọ Atiku Abubakar, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi gẹgẹ bi ọmọ oye lati dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa.

Nibi eto idibo abẹle ti ẹgbẹ naa ṣe ninu gbọngan awọn akọroyin to wa niluu Abẹokuta lonii, Ọjọru, Wẹside ni a gbọ pe wọn ti kede Ṣowunmi sita.
 
Ibo mẹrinlelaadọta le lẹẹdẹgbẹta la gbọ pe Ṣowunmi fi jawe olubori laaarin awọn akẹgbẹ rẹ bi i Ọnarebu Ladi Adebutu toun ni ibo mẹẹdogun, ati Ọtunba Jimi Lawal toun ni ibo ọgbọn.

Nigba to n kede Ṣẹgun Ṣowunmi, alaga ajọ eleto idibo to ṣagbatẹru eto idibo abẹle naa, Ọnarebu Abayọmi Daniel sọ pe awọn oludije
728 ni wọn fi orukọ silẹ, nigba to jẹ pe awọn 702 ni wọn dibo

Nigba to n dupẹ, Ṣẹgun Ṣowunmi ninu ọrọ rẹ sọ pe inu oun dun pupọ lati jẹ ọmọ oye ti yoo jade du ipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2023 to n bọ lọna.
 
O wa tẹnu mọ ọn wi pe oun yoo sa ipa oun lati ri i pe awọn gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣakoso lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI