Atiku ko le di aarẹ Naijiria lailai - Ohanaeze pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, May 30, 2022

Atiku ko le di aarẹ Naijiria lailai - Ohanaeze pariwo sita


Ẹgbẹ ọmọ ilẹ Igbo lapapọ kaakiri agbaye, iyẹn Ohanaeze Ndigbo Worldwide, ti sọ pe oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar kan n tan ara rẹ jẹ lasan ni, nitori pe awọn ko le dibo fun un, ati pe ko le di aarẹ orileede yii lailai.
 
Awọn ọmọ ẹgbẹ Ohanaeze yii ni wọn sọrọ naa lati fi bu ẹnu atẹ bi Atiku Abubakar ṣe jawe olubori nibi idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.
 
Wọn ni awuruju ati iwa magomago to pọ lo ṣẹlẹ nibi eto idibo ọhun, eyi ti awọn ẹya Hausa wo finnifinni
 
N'igba to n sọrọ, akọwe ẹgbẹ Ohanaeze lapapọ, Mazi Okechukwu Isiguzoro, sọ pe ẹya Igbo yoo dide lati tako Atiku, to si tun fi kun un pe awọn ko ni i gba ipolongo rẹ laaye nilẹ wọn, iyẹn  South-East.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI