Ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkanla tun ha l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 29, 2022

Ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkanla tun ha l'Abẹokuta


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Ṣikun bayii lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkanla kan, ti a gbọ pe wọn lọwọ si pipa ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọlaoṣebikan Tẹjuosho l'ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii.

Tẹjuosho la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye yii pa danu lagbegbe Isalẹ-Abẹtu to wa niluu Abẹokuta, ipinle naa.

Quadri Ogunsanya ti inagijẹ re n jẹ Oguns; Jamiu Kẹhinde ti wọn tun n pe ni General Smart ati Adenẹkan Samuel, toun naa n jẹ Adiye lọwọ tẹ.

Awọn yooku ni Waris Ismail, Ọlamilekan Hamsat ti won tun n pe ni Diara, Bamidele Waliu, Makinde Azeez, Makinde Ifajimin, Makinde Fashakin, Makinde Faleke ati Ajeifa Arifaṣọpẹ la gbọ pe agbegbe Itoku lọwọ ti tẹ wọn.

Ibi ti wọn ti n palẹmọ lati da wahala silẹ lagbegbe Itoku lọwọ palaba wọn ti segi, lẹyin olobo to ta ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa.

Nigba to n f'idi rẹ mulẹ fun AWIKONKO, Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa sọ pe yatọ si Tẹjuosho ti awọn wọnyii pa, iwadii tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ni wọn pa Habib Mego ati School Boy lagbegbe Omida niluu Abẹokuta laipẹ yii.

Oyeyẹmi sọ pe gbogbo wọn lo ti jẹwọ bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn lẹyin ọpọlọpọ ifọrọwanilẹnuwo.

Bẹẹ lo jẹ ko ye wa pe ọga awọn, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii kikun tubọ tẹsiwaju lati ri i pe ọwọ ṣikun ofin tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku ti wọn si n jaye familete-ki-n-tutọ kaakiri ipinlẹ naa.

Bankọle wa kilọ fun gbogbo obi ati alagbatọ lati tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, ki wọn si yago fun iwa ọdaran to le mu ki wọn ko si pampẹ ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI