Awọn to n da idọti sinu gọta n'ipinlẹ Ogun yoo bẹrẹ sii kabamọ - Ijọba ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 3, 2022

Awọn to n da idọti sinu gọta n'ipinlẹ Ogun yoo bẹrẹ sii kabamọ - Ijọba ipinlẹ Ogun


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti ṣeleri wi pe awọn to n da idọti s'awọn ibi ti ko yẹ, ni yoo bẹrẹ si i foju winna ofin ijọba bayii, nitori pe ohun ti ko bojumu to ni, ati pe awọn gbọdọ ri ọwọ iwa ibajẹ bọlẹ patapata.
 
Wọn ni ki gbogbo awọn to n da ilẹ tabi idọti s'awọn inu gọta tabi gbogbo ibi ti omi n gba kọja ni wọn n ṣakoba fun omiyale ati agbara ya ṣọọbu to n ṣẹlẹ kaakiri.
 
Bakan naa ni wọn tun fi kun un ọrọ wọn wi pe opin ti deba dida ilẹ ati idọti sẹgbẹ opopona kaakiri ipinlẹ ọhun.

Ọgbẹni Ọla Ọrẹsanya to jẹ amnugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Ogun lo sọ eyi di mimọ lakoko to n ṣabẹwo s'awọn agbegbe kaakiri, paapaa n'ijọba ibilẹ Ifọ.
 
Ọrẹsanya sọ pe ijọba ko le laju silẹ mọ lati maa jẹ ki awọn perete laaarin ilu maa ṣakoba fun awọn alaimọkan nipa eto ilera, to si ni dida idọti s'opopona n ṣakoba nla fun eto ilera.
 
Siwaju si i lo wa gba awọn to n da idọti s'opopona ati inu gọta ti omi n gba kọja lati dẹkun rẹ bayii, tabi ki wọn f'oju winna ofin ijọba to n ri sọrọ eto ayika.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI