Ramadaani: Irun Yidi alaafia waye ni Kwara, l'awọn araalu ba n gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 3, 2022

Ramadaani: Irun Yidi alaafia waye ni Kwara, l'awọn araalu ba n gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq


Pẹlu idunnu ati ayọ l'awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Ilọrin fi n gbe oṣuba rabandẹ fun Gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lori bi eto irun Yidi fun ti aawẹ Ramadaani ṣe waye nirọrun.

Bẹ o ba gbagbe, lọdun to kọja la gbọ pe awọn janduku lọ da eto irun naa ru, ti wọn si le awọn eeyan lere, koda ti awọn eeyan tun farapa yanna-yanna.


Lọdun yii, a gbọ pe Gomina AbdulRazaq ti pese eto aabo to peye fun gbogbo awọn araalu, paapaa awọn to wa gba adura igbẹyin fun ti aawẹ Ramadaani to ṣẹṣẹ pari ni Yidi agba to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe sẹ ni gbogbo awọn janduku ti wọn ti n gbero lati dabaru eto irun naa fa ọwọ aago wọn sẹyin nigba ti wọn ṣakiyesi pe ko ni s'aaye fun wọn lori ipinnu buruku ti wọn ti ṣe silẹ.

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọlẹyin Anọbi ni wọn jade lọpọ yanturu lati lọ kirun, ti wọn si dupẹ lọwọ Ọlọrun Allah to fun wọn l'anfaani lati kopa ninu aawẹ t'ọdun yii.


Lara awọn to wa ni Yidi lọjọ Aje, Mọnde ana ni Gomina AbdulRahman Abdulrazaq; Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, ti awọn ọba alade kọwọrin pẹlu ẹ.

Awọn aṣofin, aṣoju-ṣofin, alẹnulọrọ, ọtọkulu, to fi mọ awọn eeyan jankan-jankan ni wọn peju pesẹ sibẹ.

Lẹyin eto adura naa l'awọn araalu bẹrẹ si i gbe oṣuba kare f'AbdulRazaq lori bi eto ọhun ṣe lọ geerege.

Imaamu agba t'iluu Ilọrin, Sheikh Muhammad Bashir la gbọ pe o lewaju lati dari irun pipe nibẹ.

Nigba to n b'awọn eeyan sọrọ, AbdulRazaq gba awọn eeyan lamọran lati tẹsiwaju ninu iwa rere wọn, ki wọn ri i daju pe wọn n tẹle ofin ati ilana ti Allah la kalẹ fun wọn.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI