Lẹyin t'awọn afọbajẹ fa ọmọ oye kalẹ, wahala min tun dide lori ipo ọba Owu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 2, 2022

Lẹyin t'awọn afọbajẹ fa ọmọ oye kalẹ, wahala min tun dide lori ipo ọba Owu


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni ko ti i sẹni to le sọ pato ẹni ti yoo gun ori apere Olowu t’ilu Owu niluu Abẹokuta, sibẹ, ojoojumọ ni wahala ọkan-o-jọkan n dide, lori b’awọn agboole ti ipo naa kan ṣe bẹrẹ si i gbe ara wọn lọ sile ẹjọ, ti wọn si tun n f’ẹsun kan ara wọn.

Laipẹ yii ni awọn iwe ẹsun kan tun tẹ AWIKONKO lọwọ, nipa wipe wọn fẹẹ fi ọmọ ale jẹ Ọba ilu naa.

Latigba ti Olowu ana, Ọba Adegboyega Dosunmu, Amọroro keji ti waja lọjọ kejila, ọdun 2021 l’awọn afọbajẹ at’awọn oloye ilu naa ti n gbe igbesẹ lati fa ọmọ oye kalẹ, paapaa awọn idile ti ipo ọhun tọ si naa ti n dide.

Idile mẹfa ọtọọtọ la gbọ pe wọn n j’ọba niluu Owu, awọn naa si ni Amọroro, Otetila, Ayọloye, Akinjọbi, Akinoṣo ati Lagbedu. Ṣisẹ n tẹle si ni wọn fi n jẹ Ọba Olowu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ti wọn si ni idile Otetila ni ipo ọhun kan bayii, lati ti Ọba Dosunmu lati idile Amọroro waja, iyẹn lẹyin ọdun mẹrindinlogun lori itẹ.

Ọjọru, Wẹside, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹta, ọdun ti a wa yii la gbọ pe awọn afọbajẹ ilu Owu, ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria lewaju wọn ṣe ayẹwo ati ifọrọwerọ fun gbogbo awọn meje to jade lati fi erongba wọn han si ipo naa.

Lẹyin ayẹwo la gbọ pe wọn yan Ọmọọba Saka Adelọla Matẹmilọla gẹgẹ bi ẹni ti oṣuwọn rẹ kun julọ laaarin awọn meje ọhun.

Ẹwẹ, iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe lẹyin ti wọn kede Ọmọọba Matẹmilọla gẹgẹ bi ọmọ oye to perege julọ, la gbọ pe awọn Ọmọọba meji kan dide lati tako ipinnu awọn afọbajẹ naa, ti wọn si lẹni ti wọn fa kalẹ ki i ṣe ojulowo ọmọ Owu, Abẹokuta.

Ọmọọba Tajudeen Adelani ati Ọmọọbabinrin Aminat Adeṣina la gbọ pe wọn kọ iwe ẹsun ranṣẹ s’ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun, nibi ti wọn ti n sọ pe Ọmọọba Matẹmilọla ti wọn fẹẹ lo ki i ṣe ọmọ Owu, bi ko ṣe pe ajoji ni.

Lara awọn meje ti wọn dide lati idile Otetila naa ni: Biṣọọbu ijọ Aguda, Ọmọwe Adegbemi Adewale to wa lati inu ẹbi Ile Aderinoye, ẹni ti a gbọ pe ibo ẹgbẹrun kan le ni mẹtadinlọgbọn (1,027) lo ni lẹyin gbogbo ayẹwo awọn agboole; Ọmọọba Adelani Ọladimeji lati inu ẹbi Ọmọleẹfọn; Ọmọwe Saka Adelọla Matẹmilọla, lati inu agboole Ile Soke ati Ọmọọba Ọlatidoye Ọlaniyi, lati inu agboole Soke.

Awọn yooku ni Ọmọọba Adeyanju Bakinson lati inu agboole Ile Otopo; Ọmọọba Simeon Ṣoyẹle, lati inu agboole Ile Lumọsa ati Ọmọọba Adeṣina Adelani lati inu agboole Ile Soke.

Lẹyin ayẹwo t’awọn afọbajẹ ilu Owu ṣe la gbọ pe wọn fi esi ranṣẹ s’ile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, ki wọn le tẹsiwaju nipa gbigbe ade ati ọpa aṣẹ f’ẹni ti wọn mu.

AWIKONKO gbọ pe ni kete t’awọn afọbajẹ ti fi esi ranṣẹ s’ijọba l’awọn Ọmọọba lati inu agboole meji ọtọọtọ ti kọwe ẹsun lati fi tako ipinnu awọn afọbajẹ, ti wọn si lẹni ti wọn fa kalẹ ki i ṣe ojulowo ọmọ bibi ilu Owu.

Ninu iwe ẹsun ti Ọmọọba Tajudeen Adelani lati inu agboole Ọmọleefọn kọ lọjọ karun-un, oṣu kẹrin to kọja yii lo ti f’ẹsun kan Ọmọọba Saka Matẹmilọla wi pe ko wa lati agboole Ile Soke, ti awọn ẹri si wa. O ni o ṣeni laanu wi pe awọn afọbajẹ gboju fo inu agboole ti ọkunrin naa ti wa, eyi to sọ pe ko bojumu to.

Ọmọọba Adelani sọ pe ọmọ bibi agbegbe Ariwa Ibadan, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni Ọmọọba Matẹmilọla ti wa, ki i ṣe Owu, to si l’oun ni ọpọlọpọ ẹri to f’idi rẹ mulẹ.

Bakan naa, ninu iwe ẹsun tirẹ to te AWIKONKO lọwọ, Ọmọọbabinrin Adeṣina lati agboole Aderinoye sọ pe Ọmọọba Matẹmilọla ko yẹ lẹni to le wa lati ilu Ibadan lati du ipo Olowu, to si n bẹ ijọba lati tete gbe igbesẹ ko to pẹ ju.

Nigba to n fesi si ẹsun ti wọn fi kan an, Ọmọọba Matẹmilọla sọ pe lotitọ ni pe ilu Ibadan ni wọn bi oun si, ti mo si ni iwe ofin (affidavit) to sọ pe ibẹ ni wọn bi mi si, ṣugbọn iyẹn ko sọ pe mi o ki i ṣe ọmọ Owu, nitori pe iyatọ wa laaarin ibi ti wọn bi eeyan si, ati ibi ti mo toun ti wa.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
“Ohun ti mo n sọ ni pe mo ni iwe ẹri (affidavit) to sọ pe Ibadan ni wọn bi mi si, mo si ni iwe ibi ti wọn bi mi si (birth certificate), eyi to jẹ ilu Ibadan. Mi o ni ohunkohun lati sọ lori ọrọ naa mọ wi pe boya mi o kii ṣe ọmọ Owu."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI