'Paracetamol', ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ti wọn n wa tipẹ l'Abẹokuta ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 2, 2022

'Paracetamol', ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ti wọn n wa tipẹ l'Abẹokuta ti ha o


Orin ọpẹ l'awọn ara ati olugbe ilu Abẹokuta si Ifọ nipinlẹ Ogun mu sẹnu ni kete ti wọn gbọ pe ọwọ ọlọpaa ipinlẹ naa ti tẹ ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Rotimi Adebiyi, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si 'Paracetamol'.

A ri i gbọ pe nnkan bi agogo kan aabọ oru ọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja yii lọwọ tẹ Paracetamol ninu ile ẹ to n gbe niluu Ifọ, ijọba ibilẹ Ifọ.

Wọn ni awọn ọlọpaa SWAT ni wọn lo ka Paracetamol mọ ile, lẹyin olobo to ta wọn wi pe o wa nile lọjọ naa, lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti wọn ti fi n wa a.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni Paracetamol, oun si lo maa n da agbegbe Abẹokuta ati Ifọ laamu nipa pipa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako rẹ. Ọpọ ẹmi ni wọn lo ti tọwọ rẹ bọ sọnu.

Bakan naa la tun gbọ pe sẹ ni Paracetamol yoo fi ilu Ifọ to fi ṣe ibugbe silẹ, ti yoo si wa silui Abẹokuta lati wa da wahala silẹ, to ba si ti da wahala yii silẹ, ṣe ni yoo tun na papa bora sibi to n farapamọ si.

Oriṣiriṣi oogun abẹnugọngọ ati ibọn ilewọ kan to ni ọta ibọn ninu, to fi mọ egboogi oloro ati ada ni wọn gba lọwọ ẹ ni kete tọwọ palaba rẹ segi.

Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe ọga awọn, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori Paracetamol ko to di pe wọn lọ fi oju rẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI