Ọdun mẹta AbdulRazaq ti ko ire to pọ wọ ipinlẹ Kwara - 'fọlakẹ AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 31, 2022

Ọdun mẹta AbdulRazaq ti ko ire to pọ wọ ipinlẹ Kwara - 'fọlakẹ AbdulRazaq


Iyawo Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, Arabinrin Ambasidọ Olufọlakẹ AbdulRazaq ti sọ pe awọn iṣẹ akanṣe ati idagbasoke ti gomina ti mu wọ ipinlẹ Kwara laaarin ọdun mẹta to gbajọba ti fi han daju pe ọjọ iwaju ipinlẹ naa yoo dara.
 
O ni ipo ti ipinlẹ Kwara wa lakoko yii ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ wi pe ko tun le pada lọ s'oko ẹyin mọ, nitori pe iwaju ni yoo maa lọ, ti yoo si maa lewaju laaarin awọn akẹgbẹ rẹ.
 
Ninu atẹjade to gbe sita lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un ti a wa yii, Arabinrin Afọlakẹ AbdulRazaq sọ pe ifirajin ati diduro lori ileri pẹlu ipinnu lo fa a ti aṣeyọri fi n wa loore-koore.
 
O tẹ siwaju pe awọn ayipada yii lo waye loriṣiriṣi ẹka bi i ilera, eto-ẹkọ, iṣẹ ilu ati awọn ẹka to ṣe pataki, eyi to fi n pe awọn ọdọ lati maa wo awokọṣe Gomina wọn, nitori pe ifarajin lo ṣe pataki ninu iwa ọmọluabi.

Bakan naa lo gba gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lamọran lati maa gbaruku ti ijọba Gomina AbdulRazaq ki iṣẹ idagbasoke le tubọ kẹsẹjare.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI