Awọn ogbologbo adigunjale l'Ekoo ree - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 6, 2022

Awọn ogbologbo adigunjale l'Ekoo ree


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede sita wi pe ọwọ awọn ti tẹ awọn gendekunrin meji kan ti wọn fura si wi pe wọn niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ lori afara Apọngbọn to wa lagbegbe Ebute-Ero nipinlẹ naa.
 
Mustapha Mohammed ati Abdullahi Buba lorukọ awọn mejeeji ti a gbọ pe ọwọ palaba wọn segi ni nnkan bi agogo meji kọja iṣẹju mẹẹdogun oru, iyẹn lakoko ti wọn n digunjale lọwọ.
 
Nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Benjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe ọpọlọpọ ẹru ti wọn ti digun gba lawọn ti ri gba lọwọ wọn.
 
O ni ọkada Bajaj kan, tẹlifiṣan LG, ẹru mẹrindinlaadọrin ti wọn ra lori ẹrọ ayelujara ti Jumia, kọmputa alagbeka HP kan, baagi iyẹfun kan, ati kini ti wọn fi n ge irin l'awọn gba lọwọ wọn l'Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja yii.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiọdun Alabi nigba to n ṣeleri wi pe awọn mejeeji yii yoo f'oju ba ile-ẹjọ, o fi ye wa pe oun ko ni i gba iwa ọdaran laaye, to si fidi rẹ mulẹ pe ojoojumọ loun yoo maa gbogun ti gbogbo awọn to ba fẹẹ sọ ipinlẹ naa di buba idigunjale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI