Ọjọ Iwaju Rere: AbdulRazaq ṣi'ṣọ loju bi ọjọ iwaju ilu Ilọrin yoo ṣe ri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 13, 2022

Ọjọ Iwaju Rere: AbdulRazaq ṣi'ṣọ loju bi ọjọ iwaju ilu Ilọrin yoo ṣe ri


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'Ọjọru, Wẹside, ọjọ kọkanla, oṣu karun-un, ọdun 2022 ti ṣiṣọ loju bi ọjọ iwaju ipinlẹ Kwara, paapaa ilu Ilọrin yoo ṣe ri, ti yoo si rẹwa ju bo ti wa bayii lọ.
 
Ọjọ iwaju naa ti wọn pe ni Master Plan ni wọn fi n ṣe apejuwe bi ilu Ilọrin yoo ti ṣe maa figagbaga pẹlu awọn ilu to rẹwa julọ lorileede Naijiria, paapaa kaakiri agbaye.
 
Nibẹ si la gbọ pe awọn eeyan kaakiri agbaye yoo ti maa lọ sibẹ fun irin-ajo afẹ, eyi ti yoo tun jẹ ki eto ọrọ aje ipinlẹ ọhun dagbasoke ju bo ti wa tẹlẹ lọ.
 
Nigba to n ṣoju gomina nibi afihan naa, igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi jẹ ko di mimọ pe agbekalẹ ọjọ iwaju naa ni yoo jẹ idagbasoke ati ilọsiwaju maa de ba ilu Ilọrin, ti wọn lo sunmọ Alujọnna.
 
O ni agbekalẹ ọhun ni yoo fun awọn ijọba to ba n gbakoso lẹyin ọdun mẹjọ Gomina AbdulRazaq ni afojusun iṣẹ idagbasoke ti wọn yoo maa tẹsiwaju, ati pe awọn nnkan naa ni yoo jẹ iwuri f'awọn iran to n bọ lọjọ iwaju.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI