Amofin Ibrahim di Kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ n'ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 13, 2022

Amofin Ibrahim di Kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ n'ipinlẹ Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu Amofin Senior Ibrahim Sulyman gẹgẹ bi adajọ agba ati Kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ fun ipinlẹ Kwara, to si ni iyansipo rẹ bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lai fi akoko ṣofo.
 
Ọjọru, Wẹside, to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq bu ọwọ lu Amofin Sulyman gẹgẹ bi Kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ n'ipinlẹ naa, lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ akikanju to ti ṣe l'ẹka eto idajọ.

AWIKONKO gbọ pe ọkunrin naa ni Kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ agba, iyẹn Tertiary Education, ko to di pe wọn yan an s'ipo naa.

Ọdun 2008 ni Sulyman kẹkọọ gboye ni fasiti imọ ofin ti Ahmadu Bello to wa niluu Zaria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI