Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ṣe abẹwo si Sunday Igboho ni Bẹnnẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 1, 2022

Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ṣe abẹwo si Sunday Igboho ni Bẹnnẹ


Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ti ṣe abẹwo si olori ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho nile rẹ to wa niluu Cotonou, orileede olominira Bẹnnẹ.

AWIKONKO gbọ pe oni, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-ni-in, oṣu karun-un, ọdun 2022 ni Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ṣe abẹwo si Sunday Igboho lẹyin to kuro lahamọ ijọba Bẹnnẹ.

Lara awọn to tun wa nibi abẹwo ọhun ni Ọjọgbọn Banji Akintoye, olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI