Awọn oṣiṣẹ ni igilẹyin ọgba fun idagbasoke gbogbo orileede lagbaye - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 1, 2022

Awọn oṣiṣẹ ni igilẹyin ọgba fun idagbasoke gbogbo orileede lagbaye - AbdulRazaq


Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq ti gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata lapapọ, iyẹn awọn oṣiṣẹ ijọba ati ti ileeṣẹ aladani lori ipa ti wọn n ko lori idagbasoke orileede yii, paapaa eto ọrọ aje.
 
Ninu atẹjade ti gomina fi sita laaarọ oni, ọjọ Aiku, Sannde to jẹ ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ kaakiri agbaye lati fi ki wọn nipasẹ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye, AbdulRazaq sọ pe inu oun maa n dun nigba ti awọn oṣiṣẹ ba n tẹle ilana ijọba.
 
O ni awọn oṣiṣẹ jẹ igilẹyin ọgba fun gbogbo orileede to n ni idagbasoke kaakiri agbaye, paapaa ni orileede bii ti Naijiria, nipa ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba.

Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe gbogbo oṣiṣẹ lo le jẹri si i wi pe ijọba oun n sa ipa pati ri i pe wọn n gba ẹtọ wọn labẹ ofin lasiko.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI