Iyawo gomina ipinlẹ Kwara, Arabinrin Olufọlakẹ AbdulRazaq ti fi da gbogbo awọn oludije si ipo oṣelu labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ naa wi pe ki wọn lọ f'ọkan balẹ nitori pe omi tuntun yoo ru lasiko oṣelu to n bọ lọna.
Olufọlakẹ AbdulRazaq lo sọ eyi di mimọ lakoko to n gba gbogbo awọn oludije naa lalejo ni ọfiisi rẹ to wa nileegbe gomina niluu Ilọrun, ipinlẹ naa laipẹ yii.
Kọmiṣanna tẹlẹ ri f'ọrọ eto ẹkọ, Hajia Saadatu Modibo Kawu to lewaju igbimọ awọn oludije l'obinrin lẹgbẹ oṣelu APC, ẹni toun naa fẹẹ dije sọ pe ifọwọsowọpọ ati atilẹyin iyawo gomina l'awọn n fẹ.
Nigba to n sọrọ, Ambasadọ AbdulRazaq sọ pe inu oun dun pupọ lati ri i pe awọn obinrin naa dide lati ja fun ẹtọ wọn nipa didide lati jade du ipo oṣelu, to si ni ipo oṣelu ko si fawọn ọkunrin nikan.
Lara awọn to wa nibẹ ni: Hajia Saadatu Moddibo Kawu (Ilorin South), Hajia Lawal Arinola (Ilorin East), Rukayat Motunrayo Shittu (Owode/Onire), Hajia Basheerat Abdulrazaq (Ajikobi/Alanamu) Hajia Tundu Alanamu (Ajikobi/Alanamu), Hajia Mariam Imam (Edu), Hajia Mariam Yusuf (Ilorin West/Asa) Hajia Mariam (Afon), Hajia Bolajoko Bello (Ilorin South), ati Hajia Monsurat (Moro).
No comments:
Post a Comment