Oriire nla! Sẹnetọ YAYI di Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 12, 2022

Oriire nla! Sẹnetọ YAYI di Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ayẹyẹ ifinijoye Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Lagos West nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Sẹnetọ Sọlomọn Ọlamilekan Adeọla t'ọpọ awọn eeyan mọ si YAYI, gẹgẹ bi Arẹmọ Ọba ilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ Abamẹta ti i ṣe Satide, ọsẹ yii la gbọ pe Olu Ilaro, Ọba Gbadewọle Kẹhinde Olugbenle fẹẹ fi oye naa da YAYI lọla, gẹgẹ bi ojulowo ọmọ bibi ilu naa.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ oludamọran pataki fun ọkunrin naa lori eto iroyin fi sita laipẹ yii, lo ti sọ pe wọn yoo tun lo ayẹyẹ ọjọ naa lati fi saami ayẹyẹ ọdun kẹwaa, ti Ọba alaye ilẹ Yewa,  Ọba Kẹhinde Olugbenle, de ori itẹ awọn baba-nla rẹ.
 
Nibẹ si ni wọn yoo tun ti ṣe ifilọlẹ iwe itan igbesi-aye Ọba Olugbenle.
 
Lara awọn ti yoo ṣe ifilọlẹ iwe ọhun ni; Alaaji Aliko Dangote, Ahmed Lawan, to jẹ aarẹ ile igbimọ aṣofin orileede yii, ati Oloye Kessington Adebutu.

A o ranti pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021, ni awọn igbimọ lọbalọba nilẹ Yewa, kọ lẹta si Yayi pe awọn fọwọ si Arẹmọ Yewa lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, nitori awọn ilakaka ẹ to ti ṣe lati mu idagbasoke ba ilẹ Yewa lapapọ.

Loju ẹsẹ ti wọn ni aṣofin ọhun ti gba lẹta naa ti Ọba Olugbenle, gẹgẹ bi Olu Yewa, fọwọ si loun naa ti gba apọnle ati iyi ti wọn fun naa.

Lara awọn ti wọn n reti lọjọ naa ni Aarẹ ile igbimọ aṣofinAhmad Lawan, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ,to jẹ Gomina ipinlẹ Ogun, Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣọba, Ọtunba Gbenga Daniel,Ọgbẹni Boss Mustapha,akọwe ijọba apapọ, Ọọni Ile- Ifẹ, Ọba Adeyeye Ogunwusi atawọn eeyan jakanjakan ni wọn n reti lọjọ naa.

Bakan naa la gbọ pe wọn yoo tun fi iyawo Yayi, Temitọpẹ jẹ Yeye Arẹmọ,Ọtunba Akeem Ade Adigun(Sokopao) yoo joye Apagunpọtẹ ilẹ Yewa, Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun naa yoo jawe oye Oluọmọ ati Salmot Badaru, igbakeji Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun naa yoo joye Bẹẹrẹ ilẹ Yewa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI