Gbogbo awọn Ọba kaakiri ipinlẹ Kwara ni wọn ti sọ pe ko si ẹni meji t'awọn yoo ṣatilẹyin fun, fun ipo gomina ipinlẹ naa l'ọdun 2023, bi ko ṣe pe ki Gomina AbdulRahman Abdulrazaq pada s'ipo lẹẹkeji.
Wọn ni iṣakoso Gomina AbdulRazaq latigba to ti de ori ipo lo n tẹ awọn lọrun, ti wọn si l'awọn fẹ ko pada s'ipo naa lati le pari awọn akanṣe iṣẹ to n ba lọ.
Laipẹ yii ni gbogbo awọn Ọba alaye n'ijọba ibilẹ Ariwa ati Guusu ipinlẹ naa f'orikori, ti wọn si ni Gomina AbdulRazaq yẹ lẹni to n pada s'ipo lati tẹsiwaju awọn iṣẹ rere to bẹrẹ lati bi ọdun mẹta sẹyin.
Wọn ni gbogbo ẹka ati agbegbe, to fi mọ igberiko kaakiri ipinlẹ ọhun ni Gomina AbdulRazaq ti ṣiṣẹ akanṣe lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe laaarin asiko to fi n de ijọba.
AWIKONKO gbọ pe ilu Ilọrin l'awọn ọba alaye naa ti sọrọ yii lakoko ti wọn ṣabẹwo si Gomina AbdulRazaq, iyẹn lẹyin wakati mejidinlaadọta ti olori awọn ọba ilẹ Kwara, Ẹmir t'ilu Ilọrin, Ọmọwe ti kọkọ ṣe abẹwo si gomina wọn, nibi to ti n f'ọkan rẹ balẹ wi pe oun yo ṣatilẹyin fun un.
No comments:
Post a Comment