"Mo ki awọn ọmọ iya wa ninu ẹsin Islam, paapaa julọ awọn adari ẹsin naa n'ipinlẹ Kwara, Ẹmir tilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari. Adura mi si Allah ni pe ko tẹwọ gba gbogbo isin wa, ati gbogbo otitọ wa lakoko ati lẹyin Ramadaani, ko si fi orileede wa si oju ọna ti yoo mu idagbasoke ba eto aabo wa. Ko fun wa ni oore-ọfẹ lati kopa ninu aawẹ Ramadaani to n bọ ninu ilera ati igbagbọ, ko si fi Al-Jannah Firdaus da wa lọla."
Wọnyi ni ọrọ adura to jade lenu gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman Abdulrazaq lonii, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-ni-in, oṣu karun-un, ọdun 2022 si gbogbo awọn musulumi kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment