Wọn ti fi ẹsun ipaniyan ati idigunjale kan mi ri - Wike - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 3, 2022

Wọn ti fi ẹsun ipaniyan ati idigunjale kan mi ri - Wike


Oludije sipo Aarẹ orileede Naijiria labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Nyesom Wike ti sọ pe awọn ọbayejẹ ti fi ẹsun ipaniyan ati idigunjale kan oun ri lakoko toun jade lati du ipo alaga ijọba ibilẹ Obio/Akpo, ipinlẹ Rivers.

Nyesom Wike, ẹni to jẹ Gomina ipinlẹ Rivers lo tu aṣiri naa lori ẹrọ amohunmaworan ti ileeṣẹ Channels, lori eto kan ti wọn pe ni Politics Today.

Wike sọ pe inu oun dun gidigidi nitori pe lẹyin gbogbo ẹsun buruku ti wọn fi kan oun nigba naa, oun tun jawe olubori.

Bẹẹ lo sọ pe irin ajo oun lati di alaga ijọba ibilẹ ki i ṣe nnkan toun le tete gbagbe nitori pe ko rọrun, paapaa bo tun ṣe ni ọrọ ile ẹjọ ninu

“Mo gbe apoti ibo lati di alaga ijọba ibilẹ Obio/Akpo lọdun 1998/9, to si jẹ pe nipasẹ oore ọfẹ Ọlọrun, mo bori. Awọn eeyan sọ pe ọkan lara awọn ijọba ibilẹ to lowo ju ni, ṣugbọn mi o fẹẹ sọ pe ohun lo lowo ju, ṣugbọn maa sọ pe ọkan lara awọn ijọba ibilẹ to ṣe pataki julọ, to si gbajumọ daadaa, ko da ti gbogbo orileede yii ko le fọwọ rọ sẹyin.

“Ṣugbọn ki n to di alaga nibẹ, ko rọrun rara nitori pe ijọba ibilẹ to wa lọkan gbogbo eeyan ni, ati awọn ti ko wa lati agbegbe ọhun.

“Nipa akọsilẹ, emi ni ẹni akọkọ ti yoo kọkọ di alaga, eyi ti ile ẹjọ to ga julọ ni lati fi ontẹ lu. Ki i ṣe ibi ti eeyan lasan kan le di alaga. Rara, ko ri bẹẹ.

“O gba mi lati lọ sile ẹjọ to ga julọ (Supreme Court) ki n to le di alaga, mo si la ọpọlọpọ iṣoro kọja. Wọn fi ẹsun ipaniyan kan mi, mi o mọ bi ọrọ mi ba ye e yin?

“Wọn fi ẹsun idigunjale kan mi. Fun idi eyi, ki i ṣe nnkan t'eeyan le lero wi pe mo le di alaga ijọba ibilẹ, ko rọrun fun mi rara.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI