Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi orukọ awọn Kọmiṣanna tuntun to fẹẹ lo ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣe agbeyẹwọn, ko to di pe wọn bu ọwọ lu awọn orukọ naa.
Lara awọn ti Gomina AbdulRazaq fi orukọ wọn ranṣẹ ni Ọmọwe Afeez Abọlọrẹ Alabi, ẹni to ti figba lan ri jade du ipo aṣoju-ṣofin lati Ilọrin East; Adenikẹ Afọlabi-Oshatimẹhin lati ijọba ibilẹ Ifẹlodun; Wahab Fẹmi Agbaje lati ijọba ibilẹ Ọffa; Gidado Lateef Alakawa lati ijọba ibilẹ Asa, ati Ibrahim Akaje lati ijọba ibilẹ Ilọrin West.
Yatọ si orukọ awọn eeyan yii ti gomina fi ranṣẹ, a gbọ pe gbogbo nnkan to ni i ṣe pẹlu igbesi aye onikaluku wọn ni ijọba tun fi ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin lati le mọ iru eeyan ti ẹnikọọkan.
No comments:
Post a Comment