Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ ọga agba Lanre Bankọle ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹfa ti wọn ti n wa tipẹtipẹ lori wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n f'ojoojumọ ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ naa, paapaa niluu Abẹokuta ati ti Ṣagamu.
A gbọ pe ilu Ṣagamu lọwọ ti tẹ awọn mẹfẹẹfa, to si jẹ pe ibẹ naa ni wọn fi ṣe ibugbe, ti a si gbọ pe awọn ti ko din ni mẹrin ni wọn ti gba ibi wahala ọhun sọda sọrun alakeji.
Rafiu Ọṣọkoya ti inagijẹ rẹ n jẹ Osama; Azeez Abiọla ti wọn n pe ni Scofield; Ogunsanwo Waheed ti wọn n pe ni 50cent, Toheeb Ayọdele ti wọn tun n pe ni Ẹmir; Kọlawọle Adegbenro ati Azeez Taiwo l'awọn mẹfẹẹfa ti ọwọ palaba wọn ti segi bayii, ti a si gbọ pe wọn ti wa nibi ti wọn ti n ṣe iwadii wọn lọwọ.
AWIKONKO gbọ pe ibi ipade ti wọn n ṣe lọwọ pẹlu erongba lati tun da wahala miran silẹ l'awọn kan ti kofiri wọn, iyẹn loju ọna Ayepe si Odogbolu, ko to di pe wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo.
Nibẹ lọwọ palaba wọn ti segi, ti wọn si ti wa lahamọ latigba naa, nibi ti wọn ti n ka boroboro lori awọn ti wọn ti pa danu, ati ohun to n da wahala silẹ, paapaa bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn yooku wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ti jẹwọ wi pe lotitọ l'awọn wa nidi bi wahala ṣe n ṣẹlẹ niluu Ṣagamu laipẹ yii, ati pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye pọmbele l'awọn jẹ, to si jẹ pe ija agbara l'awọn n ja lati ibẹrẹ ọdun yii.
Bakan naa ni wọn tun jẹwọ pe awọn l'awọn pa ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Animashaun niluu Ṣagamu, ati ẹnikan ti wọn tun pe ni Ekwe lagbegbe Sabo niluu Ṣagamu kan naa.
Yatọ si awọn wọnyi, wọn l'awọn tun pa awọn meji kan Adigun ati Elewure lagbegbe Isote niluu Ṣagamu ni ibẹrẹ ọdun yii.
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti wa paṣẹ wi pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lati ri i pe ọwọ tẹ awọn yooku wọn ti wọn ṣi wa lahamọ.
No comments:
Post a Comment