Awa ko si lara ẹgbẹ awọn to n ṣe egboogi ibilẹ o, a da duro ni - Awọn Onigunnuko pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 12, 2022

Awa ko si lara ẹgbẹ awọn to n ṣe egboogi ibilẹ o, a da duro ni - Awọn Onigunnuko pariwo sita


Apapọ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe ti Igunnuko kaakiri ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ko ni i gba igbesẹ ti ijọba ipinlẹ naa fẹẹ gbe lati fi wọn si abẹ akoso ẹgbẹ awọn to n ṣe egboogi ibilẹ, iyẹn Alternative Medicine Practitioners.

Wọn ni iṣẹṣe, paapaa iṣẹṣe ti Igunnuko da duro ni, ati pe ẹsin abalaye ni, ti ṣiṣe ogun ibilẹ naa si da duro, eyi ti wọn fi sọ pe di da wọn papọ sabẹ ẹgbẹ kan naa ko le ṣiṣẹ rara.

Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ni pe ijoba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun fẹẹ fi orukọ gbogbo awọn oniṣẹṣe at’awọn to n ṣe egboogi ibilẹ s’oju kan ṣoṣo, ki wọn le parapọ sabẹ ẹgbẹ kan.


Ofin kan naa si ni ijọba n fẹ ko de gbogbo wọn, eyi ti wọn sọ pe ko le ṣee ṣe rara.

Ṣugbọn ṣa, l’Ọjọru ti i ṣe Wẹside, ọsẹ to kọja yii l’awọn Onigunnuko naa ṣe ipade pẹlu awọn akọroyin niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti n fi ẹhonu wọn han si ijọba wi pe awọn ko le gba a lati wa labẹ akoso awọn to n ṣe egboogi ibilẹ, nitori pe ọtọọtọ ni wọn.

Nibi ipade naa ni awọn ẹgbẹ Onigunnuko yii tun ti n rawọ ẹbẹ s’ijọba lati maa fi ofin mu ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni Ọba Igunnuko n’ipinlẹ naa, ki wọn si f’oju iru ẹni bẹẹ ba ile ẹjọ, nitori pe ayederu ni iru ẹni bẹẹ jẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ àwọn Onigunnuko, Oloye Ọdunayọ Ọsanyintolu nigba to n sọrọ, sọ pe awọn ni lati tete pariwo sita, ki ijọba ipinlẹ Ogun ma lọ ṣe aṣiṣe nipa dida wọn papọ mọ ẹgbẹ àwọn to n ṣe egboogi ibilẹ.


Oloye Ọsanyintolu, ẹni to tun jẹ Sinaba f’awọn Onigunnuko n’ipinlẹ naa tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn to n ṣe egboogi ibilẹ nilo iwe ẹri gẹgẹ bi iṣẹ wọn, ṣugbọn ti eyi t’awọn n ṣe jẹ ẹsin abalaye bi awọn ẹsin yooku.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ awọn ti Oloye Dauda Adejola jẹ olori wọn, ti Oloye Akeem Kareem Ogunrinde si jẹ akọwe gangan ni ojulowo, to si ni ayederu pọmbele ni ẹgbẹ ti Tajudeen Ajilekege to n pe ara rẹ ni Ọba Igunnuko.

O ni ẹsin Igunnuko ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ jijẹ oye ọba, to si ni ki ijọba ma ṣe gba awọn nnkan ti ko jẹ otitọ gbọ ninu dida wọn papọ mọ ẹgbẹ awọn to n ṣe egboogi ibilẹ, iyẹn Traditional Medicine.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI