June 12: Adérìnókùn kọminú lórí àìsí iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́, ètò ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 13, 2022

June 12: Adérìnókùn kọminú lórí àìsí iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́, ètò ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀


Akinruyiwa tilu Owu, Oloye Olumide Aderinokun ti fi aidunnu rẹ han lori aisi iṣẹ f'awọn ọdọ, eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ lorileede Naijiria, to si ni ijọba to wa nita lakoko yii ti kuna ojuṣe wọn f'awọn araalu.

Ọjọ Aiku, Sannde ana ni Oloye Aderinokun, ẹni to tun jẹ oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba orileede yii lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP sọrọ naa jade.

Aderinokun sọrọ yii lakoko to n rin pẹlu awọn eeyan rẹ lọ sile Oloogbe Moshood Kaṣimawo Ọlawale Abiọla, ẹni to jawe olubori nibi idibo apapọ ti ọdun 1993.


Irin naa la gbọ pe wọn rin lati gbagede iṣere ti Panṣẹkẹ to wa niluu Abẹokuta lọ sile Oloogbe Abiọla to wa loju ọna aafin Agura tiluu Gbagura.

Awọn alatilẹyin ti ko din ni ẹgbẹrun meji la gbọ pe wọn kọwọrin pẹlu Akinruyiwa tilu Owu ninu irin naa to pari si agbegbe Oke-Itoku niluu Abẹokuta ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.


Nibi eto ọhun ni Oloye Aderinokun tun ti fun ọpọ awọn ọlọkada ni ẹbun epo rọbii ọfẹ lati fi mọ riri ipa ti wọn n ko lẹka eto igbokegbodo ọkọ, paapaa lakoko eto idibo.

Ninu ọrọ rẹ, Aderinokun sọ pe
"Ebi pọ niluu, ko si iṣẹ f'awọn ọdọ, awọn ọlọja ati agbẹ ko le ṣiṣẹ nitori eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ. June 12 tun ti ji dide pada nitori pe o wa lara itan gẹgẹ bi orileede. Irin yii ki i ṣe nipa ipolongo idibo. O jẹ itaniji fun awọn eeyan wa ti ko nifẹ si iṣakoso ti ko dara lorileede yii"


Bakan naa lo ṣe ileri lati maa gbaruku ti idile Oloogbe Abiọla ni gbogbo igba nipa sisọ irin naa di ti ọlọdọọdun lati maa fi ṣe iranti eto idibo ọdun 1993 to wa lara itan orileede Naijiria.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI