Àwọn ọdaràn tó ṣe ìkọlù sí ṣọọṣi Kátólìkì ti há s'ọ́wọ́ Àmọ̀tẹ́kùn l'Òndó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 24, 2022

Àwọn ọdaràn tó ṣe ìkọlù sí ṣọọṣi Kátólìkì ti há s'ọ́wọ́ Àmọ̀tẹ́kùn l'Òndó


Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka ti ipinlẹ Ondo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn ọdaran afurasi ti igbagbọ wa wi pe awọn ni wọn ṣe ikọlu si ṣọọṣi Katoliiki to wa niluu Ọwọ, ipinlẹ Ondo laipẹ yii.
 
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko darukọ wọn, ṣugbọn nibi ti wọn ti fi oju awọn ọdaran mọkanlelaadọrin han f'awọn akọroyin niluu Ondo, Akurẹ, ni ọga wọn, Akọgun Adetunji Adelẹyẹ ti tu aṣiri naa sita.
 
Akọgun Adetunji sọ pe iṣẹ ifimufinlẹ ati iwadii t'awọn ṣe lo jẹ ki ọwọ palaba awọn agbebọn naa ti wọn ṣe ikọlu si ṣọọṣi katoliki, nibi ti eeyan ti ko din ni ogoji ti dagbere f'aye, t'awọn miran si farapa yannayanna lo jẹ ki ọwọ tẹ wọn.
 
Yatọ si awọn wọnyi ti ọwọ tẹ, AWIKONKO gbọ pe ọwọ tun tẹ awọn ọdaran miran bi i adigunjale, agbebọn, ajinigbe, ọmọ ẹgbẹ okunkun, darandaran ati bẹẹbẹẹlọ.
 

Olori awọn Amọtẹkun naa sọ pe ṣe l'awọn ṣe iwadii de ibi ti awọn agbebọn ati awọn ọdaran ọhun fi ṣe buba, ko to di pe ọwọ tẹ wọn, to si ni ọpọ ninu wọn lo ti jẹwọ pe lotitọ l'awọn jẹ ọdaran.
 
Akọgun Adelẹyẹ ninu ọrọ rẹ sọ pe 
"Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin la ti wa ninu aibalẹ ọkan. Lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laipẹ yii ni awa Amọtẹkun n'ipinlẹ Ondo si ti bẹrẹ iṣẹ takuntakun lati ri i pe a mu awọon ọdaran naa jade sita fun araye lati ri.

"A tun gbọ olobo lati ọdọ awọn darandaran wi pe wọn ji awọn maalu wọn ko salọ. A ṣe iwadii wọn, a si ri i pe ọwọ palaba wọn segi, ti a si gba awọn maalu naa pada f'awọn to ni wọn."


Nibẹ lo ti wa fi ye gbogbo aye wi pe awọn yoo f'oju gbogbo awọn t'ọwọ tẹ wọnyii ba ile-ẹjọ lati gba idajọ to tọ si onikaluku wọn, nitori pe awọn ko le gba iwa ọdaran laaye n'ipinlẹ naa, paapaa nilẹ Yoruba.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI