Àìsàn 'Monkey Pox' lalẹ̀hù n'ìpínlẹ̀ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 24, 2022

Àìsàn 'Monkey Pox' lalẹ̀hù n'ìpínlẹ̀ Kwara


Ileeṣẹ eleto ilera n'ipinlẹ Kwara ti f'idi rẹ mulẹ wi pe awọn ti ṣawari ẹnikan ṣoṣo to ni aisan 'ọbọ' ti oloyinbo n pe ni 'Monkey Pox' n'ipinlẹ naa.
 
Ninu atẹjade ti Dọkita Raji Razaq to jẹ kọmiṣanna f'ọrọ eto ilera n'ipinlẹ naa fi sita laipẹ yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ la ti gbọ pe ilu Gbugbu to wa n'ijọba ibilẹ Edu ni wọn ti ri ẹni naa.
 
Wọn l'ẹni naa ti ni ibaṣepọ pẹlu awọn marun-un kan ti wọn jẹ mọlẹbi rẹ, bi i iyawo at'awọn ọmọ.
 
Ileeṣẹ eleto ilera naa jẹ ko di mimọ pe awọn ṣawari awọn to ni aisan yii lara latari iwadii ati ifimufinlẹ t'awọn n ṣe lati le tete dẹkun rẹ ko to si pe o lọ kaakiri, iyẹn latigba ti iroyin ti jade l'oṣu kẹta ọdun yii wi pe aisan naa ti de orileede Naijiria.

A gbọ pe baale ile, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn to yan iṣẹ awakọ laayo ni wọn kofiri aisan naa lara rẹ, lẹyin to sọ pe oun ni aisan iba lara, ti awọn koko kan tun su si i lara.
 
Wọn ni lati bi ọsẹ meji bayii l'awọn ti n tọju ẹni naa, koda ti wọn si tun ṣi n ṣe iwadii lati mọ awọn to ti ni nnkan ṣe pẹlu ọkunrin naa.
 
Bakan naa ni wọn tun ti fi ye wa pe ara ọkunrin naa ti n balẹ daadaa ni wọọdu kan ti wọn fi pamọ si, lati ma ba a ṣe akoba fun ọpọ eeyan l'ọsibitu ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI