Ẹ wá wo iṣẹ́ ìyanu tí Àlùbọ́sà n ṣe ní ààgọ ara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 16, 2022

Ẹ wá wo iṣẹ́ ìyanu tí Àlùbọ́sà n ṣe ní ààgọ ara


Ṣebí ohun tó bá jọnilójú, ni Yorùbá n sọ wí pé ó yanilẹ́nu. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì kan ní ìlú CHINA ti jẹ́ kó yé wa wí pé ìwádìí tuntun tí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ÀLÙBỌ́SÀ (kò báà ṣe pupa tàbí funfun) le wo ÌBÀ, Ẹ̀FỌ̀RÌ ÀBAADÌ, àti gbogbo KÒKÒRÒ ara pátá, kò báà jẹ́ kòkòrò inú eyín, inú ẹ̀jẹ̀, inú ojú tàbí èyí tó wà nínú etí. Kódà, ó n ṣiṣẹ́ fún ÒTÚTÙ àti àwọn àìsàn mìí tí n bá ẹ̀dá jà nínú ara.

Láti lo àlùbọ́sà fún ìwòsàn ara, ohun tí ẹ ó ṣe ni wí pé:-

(1) Ẹ ó la àlùbọ́sà náà sí méjì tàbí iye tí ẹ bá le làá sí.

(2) Ẹ́ wàá ṣí ojú àlùbọ́sà náà dé àtẹ́lẹsẹ̀ yín tí ẹ bá ti fẹ́ sùn lálẹ́. Lẹ́yìn èyí ni.

(3) Ẹ ó wọ àwọ̀tẹ́lẹ̀-ẹṣẹ̀ (sock) leé kó le mu dúró. Báyìí ni yóò wà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì.Kí ilẹ̀ tó mọ́, gbogbo kòkòrò àti àìsàn tó wà láàgọ̀ ara pátá ni àlùbọ́sà náà yóò ti fà jáde síta tí àlááfíà yóò sì dé bá àgò ara yín*. Ẹ wá le padà ṣe èyí níye ìgbà tó bá wù yín, kò sí ewu níbẹ̀ rárá.

Babaláwo s'óògùn àìkú fọ́mọdé, o ní kò ṣiṣẹ́. Ẹ dákun, ṣe ọmọ náà ti kú ná ni? Àwàdà lásán ni mo sebí nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ àbájáde ìwádìí náà, ṣùgbọ́n nígbà tí mo padà finmú fínlẹ̀ dáada, mo ri dájú wí pé òtító ni. Àwọn Yorùbá sìbọ̀, wọ́n ní danwò ló bí ìyá òkèrè.

Àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dán orísìí ògùn yìí wò ni àwọn ìlú òkè òkun, gbogbo wọn náà ló sì n jẹ́ri sí i wí pé a-jẹ́-bí-idán ni ògùn náà.

Oríṣìí àìsàn wo ló n ba yín jà láàgò ara, ṣé ÀWỌ́KÁ ni tàbí ARA RÍRO? Kò bá jẹ́ kòkòrò ara tàbí AKỌ IBÀ? Ẹ̀yin ẹ sáà ti fi àlùbọ́sà sí àtẹ́lẹsẹ̀ yín sùn, ó dájú wí pé ẹ ó padà fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọba ni. Àlùbọ́sà ní agbára láti gbé kòkòrò tàbí àrùn míì sínú, ìdí nìyìí tí wọ́n fi n gbà wá nímọ̀ràn láti yẹra fún jíjẹ ààbọ̀ àlùbọ́sà tí wọ́n ti gé tó ti di ọjọ́ kejì.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI