Lotitọ ni wọn ji awọn ọmọ ijọ Sẹlẹ meji gbe l'Ogun - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 15, 2022

Lotitọ ni wọn ji awọn ọmọ ijọ Sẹlẹ meji gbe l'Ogun - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f'idi rẹ mulẹ wi pe lotitọ l'awọn agbebọn kọlu ijọ Sẹlẹ kan to wa niluu Wasimi, ijọba ibilẹ Ewekoro, ti wọn si ji awọn olujọsin meji gbe salọ nibẹ.
 
DSP Abimbọla Oyeyẹmo ti jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa lo fi idi ọrọ yii mulẹ lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye to ti lọ kaakiri igboro nipa iṣẹlẹ ọhun.
 
Oyeyẹmi sọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati ri i pe wọn gba awọn Wolii naa jade kuro lahamọ awọn to ji wọn gbe.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ sọ pe nnkan bi agogo mọkanla alẹ ọjọ Aiku ti i ṣe Mọnde to kọja yii l'awọn ajinigbe naa ji Oluwaṣeun Ajọsẹ ati Dagunro Ayọbami.
 
"A ti n gbe igbesẹ lati ri i pe a gba awọn meji ti wọn jigbe naa silẹ layọ ati alaafia lai farapa. Ojuṣe ọlọpaa ni lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu kaakiri ipinlẹ yii lai bẹru.” Oyeyẹmi ṣalaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI