Ẹ wo oju Afọlabi Ademọla ti idile Adeitan Atiba fẹẹ lo lati di Alaafin Ọyọ tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 26, 2022

Ẹ wo oju Afọlabi Ademọla ti idile Adeitan Atiba fẹẹ lo lati di Alaafin Ọyọ tuntun


Idile Ọba ti Adeitan Atiba ti agboole Oniyun, n'ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn ti fa Afọlabi Adeṣina Ademọla kalẹ gẹgẹ bi ọmọ oye lati du ipo Alaafin Ọyọ to ṣofo.


Ninu lẹta ti awọn mọlẹbi naa fi ṣọwọ s'awọn Afọbajẹ ti Ọyọmesi lọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii, wọn ni Afọlabi Adeṣina Ademọla ni ẹni t'awọn n'igbagbọ pe yoo ṣ'oju wọn daadaa ninu idije ọhun.

Wọn jẹ ko di mimọ ninu lẹta naa ti wọn kọ lati ọwọ Baba Iyaji tiluu Ọyọ wi pe ẹni t'awọn fa kalẹ naa, lawọn mu ni ibamu pẹlu ilana jijẹ oye, iyẹn Atiba Descendants Chieftaincy Declaration (Ref Number 486/55, dated 8th December, 1976).
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI