Aṣiṣe nla ti mo ṣe ree l'ọjọ ti wọn mu mi ni Kutọnu - Igboho kọminu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 26, 2022

Aṣiṣe nla ti mo ṣe ree l'ọjọ ti wọn mu mi ni Kutọnu - Igboho kọminu


Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ ti ọpọ awọn eeyan mọ si Igboho ti sọ pe aṣiṣe nla to kọja oye eeyan l'oun ṣe lọjọ ti awọn ọlọpaa agbaye ti a mọ si Interpol mu oun ni papakọ ofurufu ti orileede Benin to wa niluu Kutọnu.
 
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe laipẹ lai jina, oun yoo pada si ilẹ abinibi oun to jẹ Naijiria, ti ko si s'ohun ti ijọba Naijiria yoo fi oun ṣe lẹyin toun ba pada sile oun to wa niluu Ṣoka, ipinlẹ Ọyọ.
 
Igboho lo sọrọ yii lakoko to n ba akọroyin sọrọ nile ẹ to wa niluu Kutọnu, lorileede olomira Bẹnnẹ.

Oloye naa sọ pe ka ni oun mọ pe wọn ti dẹ panpẹ silẹ f'oun niluu Kutọnu tẹlẹ ni, oun ki ba ti jẹ koun pẹlu iyawo oun, Rọpo rin lọtọọtọ, nitori pe b'awọn ṣe rin papọ lo jẹ ki ọwọ tẹ oun.
 
O ni ko si ohun to jọ pe awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS yoo fi panpẹ ofin mu oun, ti oun ba pada wa si Naijiria.
 
Lasiko to n sọrọ lori bi irinajo naa yoo ṣe jẹ, Igboho sọ pe ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ọyọ ti da oun lare.
 
O ni DSS ko laṣẹ lati mu oun tabi kede pe awọn n wa oun lẹyin idajọ ile ẹjọ naa.
 
O ni “Mo n pada bọ ni Naijiria laipẹ.”
 
Ṣaaju ni adajọ Ladiran Akintola ti ile ẹjọ giga naa ti kọkọ sọ pe bi DSS ṣe kọlu ile Igboho lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 ko ba ofin mu, ti ile ẹjọ ọhun si ni ki DSS san ogun biliọnu naira owo  gba mabinu fun iwa ti wọn wu si ati awọn dukia rẹ ti wọn bajẹ.
 
O ni “Mo ni igbagbọ ninu ẹka eto idajọ.” 
 
Nigba to n sọrọ nipa ikọlu ti DSS ṣe sile rẹ, o ni DSS atawọn agbofinro to kọlu ile oun loru ọjọ naa fẹ pa oun ni, amọ Ọlọrun lo doola ẹmi oun.
 
Lori bo ṣe ru ikọla naa la ni pato, Igboho ni akoko ko tii to lati mẹnu le ọrọ naa.
 
O ni “Ko tii to akoko lati sọrọ, asiko ọrọ ṣi n bọ.”
 
Lori iye owo to padanu lẹyin ti awọn oṣiṣẹ DSS kọlu ile rẹ, Igboho ni ko ṣe fẹnusọ.
 
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes benz ti iye rẹ to miliọnu marundinlọgọta naira, ọkọ Hilux mẹta ti ọkọọkan rẹ to miliọnu mẹtadinlogun naira, ọkọ G-Wagon ti iye rẹ to miliọnu mejidinlaadọta naira atawọn ọkọ olowo iyebiye mii ni wọn bajẹ nile oun lọjọ naa lọhun.
 
Nipa bi wọn ṣe fi si atilẹmọle ni Benin Republic, Igboho ni iyawo oun, Ropo, ni wọn kọkọ mu ni papakọ ofurufu Cadjèhoun fun nnkan bii wakati meji gbako, wọn ko si ṣetan lati fi silẹ ayafi ti oun ba yọju.
 
O ni “Lẹyin naa ni mo yọju, ti wọn si ko ẹwọn si mi lọwọ ati ẹsẹ, to ba jẹ pe mo mọ ni, n ba ti ma jẹ ki iyawo mi tẹle mi lọ si papakọ ofurufu naa.”
 
O pari ọrọ rẹ pe awọn mejeji ko ba ti rinrinajo naa lọtọtọ, amọ gbobgo rẹ ye Ọlọrun.

5 comments:

 1. Ki olorun oba ma se fi o sile,ki ole ba je ere gbogbo wahala re no igba ti orilede oduduwa ba duro.

  ReplyDelete
 2. Gbogbo igbiyanju re ko ni ja si Adam, o si jere ise re nigbati YORUBA NATION ba wa si imuse

  ReplyDelete
 3. HUUUN!!! ADISA ADEYEMO OMO WON NI IGBOHO O MO RE, OMO ALAGBADO ODE, ORO AWON AGBALAGBA LOSO PE, TI AO BA DE JESU OLUGBALA NI ADE EGUN, AO

  ReplyDelete
 4. Ete isele(quaritine ) tiwon fun oloye ogboho ni lati jeki idibo lo tan kiwon to dasile. Labe botiwu kori olorun yio dasi oro nigeria.

  ReplyDelete
 5. Hmmmmmm......... Awon Egun ni, "dee dee mirawo". Eyi ni pe ka sorase nitoripe Ile gbigbe nyo eeyan o.

  ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI