Bi iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe Onidajọ Olukayọde Ariwoọla ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede yoo bura fun gẹgẹ bi adajọ agba Naijiria lonii.
Ipinnu naa la gbọ pe o waye lẹyin ti Adajọ agba tẹlẹ, Onidajọ Ibrahim Tanko Muhammad kọwe f'ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi adajọ agba.
Lara idi pataki ti a gbọ pe o mu ki Onidajọ Tanko Mohammad kọwe f'ipo rẹ silẹ ni ti ilera ara rẹ ti ko ja geere.
Ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 1958, ni wọn bi Onidajọ Ariwoọla, to si ti f'igba kan ri jẹ adajọ agba fun ile-ẹjọ kotẹmilọrun orileede yii, ko to di pe wọn gbe e lọ si ile-ẹjọ agba.
No comments:
Post a Comment