Ibo 2023: Ẹṣin aayan l'awọn Ariwa orileede yii n gbe Tinubu gun, irọ ni atilẹyin wọn - Ọjọgbọn Akintoye pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 26, 2022

Ibo 2023: Ẹṣin aayan l'awọn Ariwa orileede yii n gbe Tinubu gun, irọ ni atilẹyin wọn - Ọjọgbọn Akintoye pariwo sita


Olori ẹgbẹ ajijangbara fun ti ominira ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe ẹṣin aayan lasan ni awọn oloṣelu iha Ariwa Naijiria n gbe Bọla Ahmed Tinubu gun lẹyin ti wọn sọ pe awọn ṣe atilẹyin fun lati di Aarẹ Naijiria lọdun to n bọ.

Akintoye ni oun gbagbọ pe laipẹ lai jina, awọn oloṣelu naa yoo kọ ẹyin si Tinubu lati ṣalitlẹyin fun ọmọ wọn to jẹ oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar.

Ọjọgbọn Akintoye lo sọ ọrọ naa ninu ifẹrọwerọ pẹlu ileesẹ iroyin BBC Yoruba lorileede olominira Benin laipẹ yii.

O ni lootọ ni pe awọn eeyan kan le ma woye pe o yẹ ki wọn jawọ ninu ọrọ Yoruba Nation lati ṣatilẹyin fun Tinubu nitori o jẹ ọmọ ilẹ Yoruba, amọ ẹtanjẹ lasan ni.

Akintoye sọ pe “Awọn kan le maa sọ pe ẹ jẹ ka ṣatilẹyin fun Tinubu nitori ọmọ Yoruba ara wa naa ni... ẹ jẹ ka dan wo boya yoo ṣe daadaa, amọ ti ẹ ba wo finni-finni, wọn kan n tan Tinubu jẹ ni.”

“Fun apẹrẹ, awọn eeyan PDP sọ pe awọn ko gbagbo ninu ki a maa pin ipo Aarẹ si ẹlẹkunjẹkun, ṣugbọn ni kete ti Atiku jawe olubori gẹgẹ ẹni ti yoo dije ninu ẹgbẹ PDP ni awọn gomina iha Ariwa ni awọn yoo ṣatilẹyin fun Tinubu.”

“Irọ ni o, wọn kan ṣatilẹyi fun Tinubu pẹlu ẹnu lasan ni, Atiku ni wọn maa dibo fun, fun idi eyi, ko tọ ki a pa ilepa wa fun Yoruba Nation ti nitori pe Tinubu fẹ du ipo Aarẹ.”
Aburo mi ni Tinubu, amọ mi o fọwọ si ko di Aarẹ

Nipa ibaṣepọ to wa laarin Ọjọgbọn Akintoye ati Bola Tinubu, Akintoye sọ pe bo tilẹ pe oun ati Tinubu kii sọrọ, amọ o da oun mọ.

O ni “Mi o ni iṣoro kankan pẹlu Tinubu, aburo lo jẹ si mi, ẹgbọn ni mo si jẹ si pẹlu, amọ ohun to jẹmilogun ni bi Yoruba ṣe maa kuro lara Naijiria, ti igbeaye irọrun yoo si de ba awọn eeyan wa.”

“Lootọ, ka ni pe nnkan n lọ bo ṣe yẹ ni, ti wọn si ni ki n lọ  mu ọmọ Yoruba to dantọ lati ṣe Aarẹ wa, mo maa mu Tinubu, amọ lọwọ yii nnkan ko ṣenu ire.”

“Wọn n pa awọn eeyan wa nilu Owo nipinlẹ Ondo, wọn n pa wọn ni Ekiti, Igangan, Ibarapa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ẹ wa sọ pe ọrọ Aarẹ lo kan, rara o!”

Akintoye sọ pe oun ko ni ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan lọdun 2023 ju ki Yoruba Nation da wa nikan.

Ijọba Buhari gbe owo tabua fun Sunday Igboiwo lati sẹ Yoruba Nation amọ o kọ jalẹ

Ni ti ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ Igboho, baba Akintoye ni ijọba orilẹ-ede Benin ti fi Igboho silẹ ko maa ba tirẹ lọ, nitori awọn ololufẹ rẹ gba tirẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, olori ileeṣẹ ọmọ Naijiria ana, Lt. Gen. Tukur Buratai, gbe owo nlan kan fun Igboho ko le pada lẹyin ijijangbara fun ominira ilẹ Yoruba amọ o kọ lati gba owo naa, bẹẹ si ni ko tọwọ bọwe ọhun.

Akintoye ni “Wọn wa gbe owo nla fun ọmọkunrin naa amọ o kọ jalẹ, melo ninu awọn ọdọ aye ode oni lo le kọ irufẹ owo bẹẹ?”

“Tukur Buratai wa ba ninu ẹwọn, o si ṣeleri ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira fun ti o ba le tọwọ bọwe kan ti Buratai gbe wa pe oun yoo dẹyin lẹyin Yoruba Nation amọ Igboho ni ko jọ.”

O yamilẹnu pe Osinbajo fẹ di Aarẹ, amọ mo mọ pe ko le wọle
Banji Akintoye

Ni ti igbiyanju igbakeji Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lati dije du ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Ọjọgbọn Akintoye ni iyalẹnu lo jẹ fun oun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, oun ko dunnu pe Ọṣinbajo padanu ipo naa, amọ ko jẹ iyalẹnu pe ko wọle.

O ni “Nigba ti wọn n sọ pe awọn ara iha Ariwa wa lẹyin Ọṣinbajo mo kan n rẹrin ni, nitori mo mọ pe Ọṣinbajo ko ni gbongbo bii Tinubu.

“Ọkan lara awọn ọlọpọlọ pipe ti a ni ni Naijiria ni Ọṣinbajo ṣugbọn ko ni gbongbo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI