Ọwọ So-Safe tun tẹ Ganiyu, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Owode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 26, 2022

Ọwọ So-Safe tun tẹ Ganiyu, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Owode


Ileeṣẹ to n pese aabo f'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun lapapọ, Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si So-Safe Corps ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Qudus Ganiyu lori ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun.
 
So-Safe Corps sọ pe ogbologbo ni Ganiyu jẹ ninu ọmọ ẹgbẹ okunkun to wa lagbegbe Owode Ẹgba, ipinlẹ naa, to si ti lewaju oriṣiriṣi ikọlu.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to fẹẹ pari yii la gbọ pe ọwọ palaba Ganiyu segi ni nnkan bi agogo mẹwaa kọja iṣẹju mẹsan aarọ. Ibi ti wọn lo ti n dunkooko mọ awọn eeyan lagbegbe Lotto to wa n'ijọba ibilẹ Owode la gbọ pe ọwọ ti tẹ ẹ.

 
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Corps, Ọgbẹni Mọruf Yusuf to gbe iroyin ọhun si wa leti sọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti Aiye ni Ganiyu jẹ
 
Mọruf sọ pe ṣaaju akoko ti ọwọ tẹ Ganiyu, o ni wọn ti kede rẹ sita tẹlẹ gẹgẹ bi i pe wọn n wa, lẹyin to na papa bora, nibi ikọlu to lewaju rẹ laipẹ yii. Awọn ọlọpaa ẹkun Redeem la gbọ pe wọn muu tẹlẹ, ṣugbọn to raaye salọ mọ wọn lọwọ.

Wọn ni bi ọwọ ṣe tẹ ẹ ni wọn ti lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI