Ìjọba bẹrẹ àtúnṣe àwọn òpópónà tó bàjẹ́ ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 21, 2022

Ìjọba bẹrẹ àtúnṣe àwọn òpópónà tó bàjẹ́ ní Kwara


Pupọ awọn opopona to ti bajẹ, ati awọn to ti dẹnukọlẹ patapata kaakiri ipinlẹ Kwara ni ijọba ti dawọ le bayii fun irọrun araalu nipa igbokegbodo ọkọ to ja geere.

Ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti jẹ ko di mimọ pe ohun ko fẹ wahala tabi idaamu fun awọn eeyan rẹ lakoko ti ọlaju ti de ba gbogbo agbaye.

Bẹ o gbagbe, laipẹ yii ni ijọba ṣẹṣẹ pari atunṣe lori ọna Geri Alimi Diamond ti wọn fi biliọnu mẹta aabọ ṣe labẹ iṣakoso to kọja, ṣugbọn ti ko pẹ to fi bajẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI