So-Safe gba ọ̀kadà tí wọ́n jígbé padà l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 21, 2022

So-Safe gba ọ̀kadà tí wọ́n jígbé padà l'Ógùn


Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti sọ pe awọn ti ri ọkada kan t'awọn adigunjals kan jigbe lagbegbe Bode-Olude, niluu Abẹokuta l'ọsẹ to kọja yii.

A gbọ pe asiko ti awọn oṣiṣẹ aabo ọhun n ṣiṣẹ aabo kaakiri ilu ni wọn l'awọn kan n gbe ọkada mẹta lọ, ti wọn si gbiyanju lati da wọn duro, lati le fi ọrọ wa wọn lẹnu wo nipa iru eeyan ti wọn jẹ, ati ibi ti wọn ti n bọ.

Wọn l'awọn eeyan naa ko duro rara, ṣe ni wọn tẹsẹ mọ irin lati salọ, eyi ti wọn lo fu awọn oṣiṣẹ So-Safe Corps naa lara ti wọn fi le wọn.

Igba ti wọn ni ninu awọn to n gbe ọkada naa salọ ri i pe ọwọ ti fẹẹ tẹ wọn, lo mu ki wọn sare bọ silẹ, lati juba ehoro, ti wọn si gbe ọkada naa silẹ lọ, iyẹn lọjọ kerindinlogun, oṣu kẹfa ti a wa yii.

Bayii ni wọn ṣe gbe ọkada naa, TVS ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 939UL lọ si ọfiisi wọn lati ṣe iwadii.

Ọjọ keji la gbọ pe ọkunrin kan, Ahmed Aina yọju pẹlu awọn iwe ẹri lati fi to wọn leti pe wọn ji ọkada oun gbe, to si jẹ iyalẹnu wi pe ọkada ọhun gan-an ni wọn gba.

Lẹyin ọpọlọpọ aridaju ti wọn f'idi rẹ mulẹ lo mu ki wọn gbe ọkada naa silẹ fun ẹni to ni i, paapaa nigba to tun sọ pe iwaju ile oun ni wọn ti jiigbe, gẹgẹ bi Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ naa ṣe sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI