Ijọba Kwara ba abẹnugọn ile igbimọ aṣofin wọn kẹdun lori iku baba rẹ, Alaaji Gwanara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 18, 2022

Ijọba Kwara ba abẹnugọn ile igbimọ aṣofin wọn kẹdun lori iku baba rẹ, Alaaji Gwanara


Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Yakubu Danladi-Salihu ti padanu baba rẹ, Alaaji Aliyu Gwanara sọwọ iku.
 
AWIKONKO gbọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni baba naa ti wọn tun n pe ni Tafarikin Borgu jade laye lẹyin aisan ọjọ ogbo ti wọn lo kọlu, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ninu lẹta ibanikẹdun ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi ranṣẹ si mọlẹbi oloogbe naa, paapaa Ọnarebu Danladi-Salihu, lo ti sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun wọn.
 
O niijọba Kwara ba gbogbo ilu Barutẹn kẹdun ọkan lara awọn agba wọn to jade laye lasiko ti wọn nilo rẹ julọ, nitori pe awọn ida rere to ti ko lawujọ ko ṣee gbagbe.

Ninu lẹta ibanikẹdun naa lo ti rọ gbogbo mọlẹbi, paapaa olori ile igbimọ aṣofin, Ọnarebu Danladi-Salihu lati mu ọkan le, paapaa bo ṣe jẹ pe oku baba wọn ki i ṣe oku ọfọ, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ baba naa to fi ara jin fun ijọsin Allah si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI