Ile-ẹjọ agba orileede yii ni awọn akẹkọọ musulumi lẹtọ lati wọ Ijaabu l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 18, 2022

Ile-ẹjọ agba orileede yii ni awọn akẹkọọ musulumi lẹtọ lati wọ Ijaabu l'Ekoo


Ile-ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria ti gbe idajọ kalẹ wi pe gbogbo awọn akẹkọọbinrin ti wọn jẹ musulumi ni wọn ni ẹtọ si lilo iborun Ijaabu n'ipinlẹ Eko lai si idiwọ kankan.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni ile-ẹjọ giga naa gbe idajọ kalẹ wi pe bi onikaluku ṣe ni ẹtọ si ẹsin wọn, naa l'awọn akẹkọọ ti wọn jẹ musulumi lẹtọ lati lo Ijaabu gẹgẹ bi ilana ẹsin wọn.
 
Ṣaaju asiko yii la gbọ pe ijọba ipinlẹ Eko ti pe ẹjọ kọtẹmilọrun ti ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ wi pe awọn akẹkọọbinrin musulumi lanfaani lati lo Ijaabu lọ sileewe wọn.
 
Awọn igbimọ eto idajọ naa, Onidajọ Olukayọde Ariwoọla, Onidajọ Kudirat Kekere-Ẹkun, Onidajọ John Inyang Okoro, Onidajọ Uwani Aji, Onidajọ Mohammed Garba, Onidajọ Tijjani Abubakar, ati Justice Emmanuel Agim lo gbe idajọ naa kalẹ niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI