June 12: 'Otogẹ' ti jẹ ka mọ pataki eto ìjọba àwa-ara-wa - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 13, 2022

June 12: 'Otogẹ' ti jẹ ka mọ pataki eto ìjọba àwa-ara-wa - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe gbigba ijọba kuro lọwọ iṣakoso ana nipinlẹ naa ti jẹ k'awọn araalu mọ pataki eto ijọba àwa-ara-wa.

AbdulRazaq sọ eyi nibi ayajọ ọjọ eto oṣelu awa-ara-wa ti June 12 to waye lọjọ Aiku, Sannde ana n'ipinlẹ Kwara.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe oun ri i daju pe awọn araalu ni anfaani si awọn idagbasoke alailẹgbẹ ti awọn iṣakoso to ti kọja lọ ko ṣe fun wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "Mo darapọ mọ gbogbo awọn alakikanju kaakiri agbaye lati saami ayajọ ayẹyẹ June 12 to jẹ ayajọ ọjọ oṣelu awa-ara-wa, ti wọn fi sọri gbogbo awọn akọni l'ọkunrin ati l'obinrin, paapaa julọ Oloogbe Moshood Kaṣimawo Ọlawale Abiọla, GCFR.

"Ọjọ yii ran wa leti abala kan ninu itan nigba ti awọn ọmọ Naijiria fi orikori, fikunlukun lati lewaju eto ijọba àwa-ara-wa pẹlu afojusun lati ni ọjọ iwaju rere fun ilẹ wa.

"Ọkan lara awọn ilakaka nibi apoti ibo, iṣakoso wa n'ipinlẹ Kwara si lọ ni ibamu pẹlu afojusun eeyan lasan to n fẹ ọpọ. Eyi si ṣalaye afojusun wa nipa fifun gbogbo ọmọ Kwara ni ẹtọ si ipilẹ lati gun oke agba, nipa pipese eto ilera gidi ati oriṣiriṣi anfaani fun gbogbo eeyan.
 
"Lẹyin ti a ti mu ipinlẹ Kwara kuro ninu jija ijọba lole awọn dukia wọn, ai san owo oṣu ati ajẹmọnu deedee...inu wa dun wi pe iṣakoso Otogẹ wa lonii ti mu ifọmọniyanṣe ati iwa ọmọluabi si ojuṣe."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI