Lotitọ ni wọn ji olori ijọ Katoliiki gbe ni Kogi - Ọlọpaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 6, 2022

Lotitọ ni wọn ji olori ijọ Katoliiki gbe ni Kogi - Ọlọpaa


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi ti f'idi rẹ mulẹ wi pe lotitọ l'awọn agbebọn kan ti ji olori ijọ Katoliki kan to wa lagbegbe Obangede, ijọba ibilé Okehi, Rev. Fr Christopher Onotu gbe, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati gba agba ojiṣẹ Ọlọrun naa silẹ lọwọ awọn ajinigbe.
 
Ọjọ Abamẹta ti i ṣe Satide, ọsẹ to kọja yii ni iroyin fi to wa leti wi pe awọn agbebọn naa ji Fr. Onotu gbe ninu ṣọọṣi to n ṣakoso rẹ.
 
Nigba to n f'idi rẹ mulẹ, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Williams Aya, sọ pe ọga awọn, Edward Egbuka ti ran awọn ọlọpa abẹ rẹ lati bẹrẹ iṣẹ iwadii, ki wọn si gba agba ojiṣẹ Ọlọrun naa silẹ lai farapa.
 
AWIKONKO gbọ pe nnkan bi agogo mẹsan alẹ l'awọn ajinigbe naa yawọ inu ṣọọṣi ọhun, ti wọn si fọ oju ferese ti wọn gba wọle sinu yara ti Ojiṣẹ Ọlọrun naa n gbe, ko to di pe wọn gbe e lọ.
 
Wọn ni aarọ ana, ọjọ Aiku, Sannde l'awọn eeyan to o mọ, lakoko ti wọn lọ gbadura aarọ kutu, iyẹn Morning Mass.
 
A tun gbọ pe ṣe ni wọn gbe mọto ojiṣẹ Ọlọrun naa lọ, ko da, ti wọn tun ko foonu rẹ mejeeji silẹ, ṣugbọn ti wọn yọ siimu ipe {SIM CARD} rẹ dani lati fi pe awọn eeyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI