Akeredolu bu sẹkun nibi ikọlu awọn agbebọn si ṣọọṣi Kátólìkì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 6, 2022

Akeredolu bu sẹkun nibi ikọlu awọn agbebọn si ṣọọṣi Kátólìkì


Beeyan ba ri gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu nibi ikọlu t'awọn agbebọn ṣe si ṣọọṣi Katoliki to wa niluu Ọwọ, l'ọjọ Aiku, Sannde ana, yoo mọ pe inu rẹ ko dun rara, eyi to mu ko bu sẹkun nibẹ.

Awọn agbebọn mẹrin kan ni iroyin fi to wa leti wi pe wọn yawọ ṣọọṣi Katoliki ọhun, iyẹn St Francis Catholic Church, to wa ladugbo Ọwa-luwa niluu Ọwọ laaarọ kutu, ti wọn si yinbọn pa awọn olujọsin nibẹ.
 
Wọn ni asiko ti wọn ni wọn n ṣe oore ọfẹ lati kadi isin nilẹ la gbọ pe awọn agbebọn ọhuun kọlu wọn pẹlu ibọn at'awọn nnkan ija oloro loriṣiriṣi.
 
Gomina Akeredolu to sare de ibi iṣẹlẹ ọhun lati ilu Abuja to wa fi aidunnu rẹ han, to si ni iwa ọdaju to kọminu l'awọn agbebọn naa hu s'awọn eeyan nibi ti wọn ti n sin Ọlọrun wọn lọwọ.
 
O bo tilẹ jẹ pe ko si ibi ti iwa buruku yii ko ti le ṣẹlẹ, sibẹ awọn ko ni i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un.
 
Lẹyin to kuro ni ṣọọsṣi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ni Gomina Akeredolu tun gba ọsibitu Ijọba apapọ, iyẹn Federal Medical Centre, FMC to wa niluu Ọwọ, nibi ti wọn ko awọn oku at'awọn to farapa nibẹ lọ fun itọju

Bakan naa lo tun yọju si aafin Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Gbadegẹṣin Ogunoye, lati ba a kẹdun ikọlu naa, to si l'awọn yoo ṣe ojuṣe wọn lati ri i pe iru nnkan bẹẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI