Mo ti gba kamu lori eto idibo abẹle to waye - Sẹnetọ Oloriẹgbẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 30, 2022

Mo ti gba kamu lori eto idibo abẹle to waye - Sẹnetọ Oloriẹgbẹ


Aṣofin agba to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kwara, Sẹnetọ Ibrahim Yahaya Oloriẹgbẹ ti sọ pe oun gba esi abajade eto idibo abẹle to waye laipẹ yii ni ipinlẹ naa, to si loun ba alatako rerto jawe olubori yọ.

Malaamu Saliu Mustapha ni iroyin fi to wa leti wi pe o jawe olubori nibi eto idibo abẹle ọhun, nibi to ti f'idi Sẹnetọ Oloriẹgbẹ janlẹ.

Nigba to n sọrọ niluu Ilọrin l'Ọjọru, Wẹside ana, o loun yoo tubọ maa tẹsiwaju lati ṣoju wọn daadaa, toun yoo si jẹ ki awọn ẹtọ wọn tẹ wọn lọwọ lasiko lai ṣe ojusaaju.

"Ọpẹ nla si Allah fun ibukun ati oju-rere rẹ lori aye mi, mo fẹẹ sọ ọ pẹlu idanuloju wi pe mo ti gba esi abajade eto idibo abẹle to waye lanaa (Tusidee) gegetbi ifẹ Allah."

Bakan naa lo tun lu alatako rẹ to jawe olubori l'ọgọ ẹnu, nigba to n ki ku oriire fun akitiyan rẹ lori bo ṣe gbegba oroke nibi eto idibo ọhun.

Yatọ si eyi, o tun ki gbogbo awọn to kopa ninu idibo naa bi i Amb. Abdufatai Yahaya Seriki, Gomina Abdulrahaman Abdulrasaq, at'awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI