Ataọja tiluu Oṣogbo, Ọba Jimọh Ọlanipẹkun ti gba gbogbo ọmọ Yoruba lamọran lati mura silẹ de ọjọ ogun, nitori pe eto aabo ilẹ Yoruba ti mẹhẹ patapata, wọn ko si gbọdọ laju silẹ ki wọn jẹ ki ogun gbe wọn lọ.
Kabiyesi ni awọn Yoruba gbọdọ dira daadaa loju ara ati ninu ẹmi lati le koju awọn agbebọn to n fojoojumọ kọlu wọn, ti wọn si n da ẹmi awọn eeyan legbodo.
Ọba Ọlanipẹkun lo sọrọ lẹyin ipade to ṣe pẹlu Aarẹ Ọna kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Abiọdun Ige Gani Adams l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana.
Nibẹ lo ti bu ẹnu atẹ ikọlu t'awọn agbebọn n ṣe kaakiri ilẹ Yoruba, paapaa eyi ti wọn ṣe ni ṣọọṣi Katoliiki ti ilu Ọwọ, ipinlẹ Ondo laipẹ yii, nibi ti wọn ti pa awọn olujọsin ti ko din ni ogoji, t'awọn miran si tun farapa yannayanna.
Ataọja ni ikọlu ti wọn n ṣe leralera ti fi han wi pe ilẹ Yoruba gangan ni ilepa wọn ti awọn agbebọn naa fẹẹ parun, ṣugbọn to ni wọn ko gbọdọ gba fun wọn.“Inu mi dun wi pe Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba wa nibi, mo si fẹẹ fi asiko yii bẹ ẹ wi pe ko gba wa silẹ kuro lọwọ awọn ọdaran agbebọn wọnyii.
“Ilẹ Yoruba n gbona jọjọ, igba ti a ba si mura silẹ funra wa, ti a gbaradi loju aye ati ninu ẹmi nikan la le gbogun ti awọn agbeọn ti wọn ti sapamọ si ẹkun ilẹ wa.”
Iba Gani Adams ninu ọrọ tirẹ sọ pe orileede yii nilo iranlọwọ pajawiri lati ọdọ awọn ẹlẹyinju aanu kaakiri agbaye.
O ni ẹgbẹ ajijangbara nilẹ Yoruba, Oodua Peoples Congress (OPC) labẹ iṣakoso oun yoo sa gbogbo ipa to ba yẹ lati ri i pe wọn gbẹsan ikọlu ti wọn ṣe siluu Ọwọ laipẹ yii.
No comments:
Post a Comment