Wọn ti tu Biṣọọbu ijọ Anglican ati iyawo rẹ ti wọn jigbe silẹ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 15, 2022

Wọn ti tu Biṣọọbu ijọ Anglican ati iyawo rẹ ti wọn jigbe silẹ o


Bo tilẹ jẹ pe ọkan Biṣọọbu kan ati yawo rẹ ti awọn ajinigbe jigbe loju ọna Jẹbba laipẹ yii ko ti i balẹ, sibẹ, idunnu nla lo jẹ fun wọn pẹlu awọn eeyan wọn lori b'awọn ajinigbe ṣe tu wọn silẹ.
 
Biṣọọbu Adeyinka Aderọgba, iyawo rẹ ati awakọ wọn l'awọn ajinigbe jigbe laipẹ yii, ti wọn si ti gba itusilẹ lẹyin wakati mejidinlaadọta ti wọn ji wọn gbe.

Gẹlẹ ti wọn gba itusilẹ la gbọ pe wọn ti ko wọn lọ si ile iwosan lati gba itọju latari wahala ati idaamu ti wọn koju lahamọ awọn ajinigbe.

Ohun ti a ko ti i gbọ bayii ni pe boya wọn san owo f'awọn ajinigbe naa ko to di pe wọn gba itusilẹ tabi wọn ko san.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI