Alake ilẹ Ẹgba fontẹ lu Aderinokun lati jade du ipo aṣofin agba l'ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 29, 2022

Alake ilẹ Ẹgba fontẹ lu Aderinokun lati jade du ipo aṣofin agba l'ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun


Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Michael Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, Okukẹnu kẹrin ti sọ pe ko si ẹlomiran to tun le ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, to kọja Oloye Olumide Aderinokun.

Oloye Aderinokun to n jade du ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lo ṣe abẹwo si Ọba Gbadebọ lonii, Ọjọbọ, Tọside ni aafin rẹ to wa lagbegbe Ake, Abẹokuta.

Nigba to n sọrọ, Alake ilẹ Ẹgba sọ pe oriṣiriṣi iroyin rere loun ti gbọ nipa Aderinokun, koda ti Kabiyesi sọ pe oyun inu gan-an mọ ẹni ti wọn n pe ni Aderinokun gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu.

Kabiyesi ni iru awọn to yẹ ki wọn yan sipo aṣoju niyẹn, nitori pe wọn yoo mu idagbasoke pupọ ba orileede, paapaa agbegbe ti wọn lọ ṣoju.
  
  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI