Ìjọba Kwara kede Fraide gẹgẹ bi ọjọ isinmi f'awọn oṣiṣẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 29, 2022

Ìjọba Kwara kede Fraide gẹgẹ bi ọjọ isinmi f'awọn oṣiṣẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn


Lojuna lati le jẹ k'awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Kwara fi orukọ silẹ fun kaadi idibo alalopẹ, iyẹn Permanent Voters Card, PVC wọn, ijọba ipinlẹ naa ti kede oni, ọjọ Ẹti, Furaidee gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ, o ni ijọba ti pa a laṣẹ wi pe ki awọn oṣiṣẹ duro sile, ki wọn le ni anfaani lati lọ fi orukọ silẹ fun kaadi idibo wọn.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje yii ni ajọ eleto idibo, iyẹn INEC kede pe eto fifi orukọ silẹ naa yoo dopin.

Ijọba wa gba gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata lamọran lati lo ahfaani isinmi naa fun fifi orukọ silẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn, ki wọn le lanfaani lati dibo yan awọn ti wọn n fẹ lọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI